orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Okùn-Ìwọ̀n Ti Jérúsálẹ́mù

1. Mó si tún gbé ojú mi, sòkè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ọkùnrin kan ti o mú okùn-ìwọ̀n lọ́wọ́ rẹ̀.

2. Mo sí wí pé, “Níbo ni ìwọ ń lọ?”O sí wí fún mí pé, “Láti wọn Jérúsálẹ́mù, láti rí iyé ìbú rẹ̀, àti iyé gígùn rẹ̀.”

3. Sì kiyesí i, ańgẹ́li tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, ańgẹ́lì mìíràn si jáde lọ pade rẹ̀.

4. Ó si wí fún un pé, “Sáré, sọ fún ọdọmọkùnrin yìí wí pé, ‘A ó gbé inú Jérúsálẹ́mù bi ìlú ti kò ní odi, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn àti ohun-ọ̀sìn inú rẹ̀.

5. Olúwa wí pé, Èmí ó sì jẹ́ odi iná fún un yíká, èmi ó sì jẹ́ ògo láàrin rẹ̀.’

6. “Áà! Áà! Sá kúrò ni ilẹ̀ àriwá, ni Olúwa wí; nítorí pé bí afẹ́fẹ́ mẹ́rin ọ̀run ni mo tú yín kákiri,” ni Olúwa wí.

7. “Gbà ara rẹ̀ sílẹ̀, Ìwọ Síonì, ìwọ tí ó ń bà ọmọbìnrin Bábílónì gbé.”

8. Nítorí bayìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Lẹ́yìn ògo rẹ̀ ni a ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kó yin: nítorí ẹni tí ó tọ́ yin, ó tọ́ ọmọ ojú rẹ̀.

9. Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ikogun fún iránṣẹ́ wọn: ẹ̀yín yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi.

10. “Kọrin kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Síónì: Nítorí èmi ń bọ̀ àti pé èmi yóò sì gbé àárin rẹ,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

11. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò dàpọ̀ mọ́ Olúwa ní ọjọ́ náà, wọn yóò sì di ènìyàn mi: èmi yóò sì gbé àárin rẹ, ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí ọ.

12. Olúwa yóò sì jogún Júdà ìní rẹ̀, ni ilẹ̀ mímọ́, yóò sì tún yan Jérúsálẹ́mù.

13. Ẹ̀ dákẹ̀, gbogbo ẹran-ara níwájú Olúwa: nítorí a jí i láti ibùgbé mímọ́ rẹ̀ wá.”