orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Olúwa Wa Jọba

1. Kíyèsí i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀, a ó sì pín ìkógun rẹ̀ láàrin rẹ̀.

2. Nítorí èmi ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí Jérúsálẹ́mù fún ogun; a ó sì ko ìlú naà, a ó sì kó àwọn ilé, a ó sì ba àwọn obìnrin jẹ́, ààbọ̀ ìlú náà yóò lọ sí ìgbékùn, a kì yóò sì gé ìyókù àwọn ènìyàn náà kúrò ni ìlú náà.

3. Nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ, yóò sì bá àwọn orílẹ̀-èdè náa jà, gẹ́gẹ́ bí í ti ìjà ní ọjọ́ ogun.

4. Ẹṣẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Ólífì, tí ó wà níwájú Jérúsálẹ́mù ni ila-oòrùn, òkè Ólífì yóò sì làá sí méjì, sí ìhà ilà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrun, àfonífojì ńláńlá yóò wà: ìdajì òké náà yóò sì sí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúṣù.

5. Ẹ̀yin ó sì ṣá sí àfonífojì àwọn òkè mi: nítorí pé àfonífojì òkè náà yóò dé Àṣàlì: nítòòtọ́, ẹ̀yin ó ṣá bí ẹ tí ṣá fún ìmímì-ilẹ̀ ni ọjọ́ Úṣáyà ọba Júdà: Olúwa Ọlọ́run mi yóò sì wá, àti gbogbo àwọn Ẹni-mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

6. Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn.

7. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ọjọ́ kan mímọ́ fún Olúwa, kì í ṣe ọ̀ṣán, kì í ṣe òru; ṣùgbọ́n yóò ṣe pé, ni àṣálẹ́ ìmọ́lẹ̀ yóò wà.

8. Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jérúsálẹ́mù ṣàn lọ; ìdájì wọn sìhà òkun ilà-oòrùn, àti ìdájì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀.

9. Olúwa yóò sì jọba lórí gbogbo ayé; ni ọjọ́ náà ni Olúwa kan yóò wa orúkọ rẹ̀ nìkan náà ni orúkọ.

10. A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Gébà dé Rímónì lápá gúsù Jérúsálẹ́mù: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jérúsálẹ́mù ṣókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Bẹ́ńjámínì títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ile ìṣọ́ Hánánélì dé ibi ìfúńtí wáìnì ọba.

11. Ènìyàn yóò sì máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ìparun mọ́; ṣùgbọ́n a o máa gbé Jérúsálẹ́mù láìléwu.

12. Èyí ni yóò sì jẹ́ àrùn tí Olúwa yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn ti ó tí ba Jérúsálẹ́mù jà; ẹran-ara wọn yóò rù nígbà tí wọn dúró ni ẹṣẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ni ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì bàjẹ́ ni ẹnu wọn.

13. Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò wà láàrin wọn; wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ ìkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ ìkejì rẹ̀.

14. Júdà pẹ̀lú yóò sì jà ni Jérúsálẹ́mù: ọrọ̀ gbogbo awọn aláìkọlà tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, góòlu, àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.

15. Bẹ́ẹ̀ ni àrùn ẹṣin, ìbáákà, ràkúnmí, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àrùn yìí.

16. Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jérúsálẹ́mù yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn Ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àṣè àgọ́ náà.

17. Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jérúsálẹ́mù láti sín Ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn.

18. Bí ìdílé Éjíbítì kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò; àrùn náà yóò wà, tí Olúwa yóò fi kọlù àwọn aláìkọlà tí kò gòkè wá láti se àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà

19. Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Éjíbítì, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́.

20. Ní ọjọ́ náà ni “MÍMỌ́ SÍ Olúwa” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ.

21. Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jérúsálẹ́mù àti ni Júdà yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rubọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kénánì kò ní sí mọ́ ni ile Olúwa àwọn ọmọ-ogun.