Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 49:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù:gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀ èdè jínjìn-nà réré:kí a tó bí mi Olúwa ti pè mí;láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi.

2. Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n,ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pamí mọ́:ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán,ó sì fi mí pamọ́ sínú àpó rẹ̀.

3. Ó sọ fún mi pé, “Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe,Ísírẹ́lì nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.”

4. Ṣùgbọ́n èmi ṣọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán;mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀ mófo.Síbẹ̀ síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sími sì wà lọ́wọ́ Olúwa,èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”

5. Nísinsìn yìí Olúwa wí péẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀láti mú Jákọ́bù padà tọ̀ mí wáàti láti kó Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú OlúwaỌlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi

6. Òun wí pé:“Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ miláti mú ẹ̀yà Jákọ́bù padà bọ̀ sípòàti láti mú àwọn ti Ísírẹ́lì tí mo ti pamọ́.Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà,kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wásí òpin ilẹ̀ ayé.”

7. Ohun tí Olúwa wí nìyìíOlùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì—sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kóríralọ́wọ́ àwọn orílẹ̀ èdè,sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ:“Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè,àwọn ọmọ ọba yóò ríi wọn yóò sì wólẹ̀,nítorí Olúwa ẹni tí í ṣe olótìítọ́,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tí ó ti yàn ọ́.”

8. Ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Ní àkókò ojú rere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn,àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́;Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn,láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípòàti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,

9. Láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá’àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’“Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nààti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.

10. Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òrùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n,tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí òòrùn kí ó pa wọ́n.Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn,tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi oríṣun omi.

11. Èmi yóò sọ gbogbo àwọn oke-ńlá mi di ojú-ọ̀nààti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé ṣókè.

Ka pipe ipin Àìsáyà 49