Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 23:7-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ó sì wó ibùgbé àwọn tí ń ṣe panṣágà lọ́kùnrin o tí ojúbọ wọn lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún Áṣérà (òriṣà).

8. Jòṣíáyà kó gbogbo àwọn àlùfáà láti àwọn ìlú Júdà ó sì ba ibi mímọ́ wọ̀n-ọn-nì jẹ́ láti Gébà sí Béríṣébà, níbi tí àwọn àlùfáà ti ṣun tùràrí. Ó wó àwọn ojúbọ lulẹ̀ ní ẹnu ìlẹ̀kùn—ní ẹnu ọ̀nà à bá wọlé ti Jóṣúà, baálẹ̀ ìlú ńlá tí ó wà ní apá òsì ẹnu ìlẹ̀kùn ìlú ńlá.

9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, àwọn àlùfáà ibi gíga kò jọ́sìn ní ibi pẹpẹ Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, wọ́n jẹ nínú àkàrà aláìwú pẹ̀lú àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn.

10. Ó sì ba ohun mímọ́ Tófẹ́tì jẹ́, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Beni-Hínómì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan tí ó lè lò ó fún ẹbọ rírú fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin nínú iná sí Mólékì.

11. Ó sì kúrò láti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sí ilé Olúwa, àwọn ẹṣin tí àwọn ọba Júdà ti yà sọ́tọ̀ sí oòrùn náà. Wọ́n wà nínú ilé ẹjọ́ lẹ́bàá yàrá oníṣẹ́ tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Nátanì-Mélékì. Jòṣíáyà sì ṣun àwọn kẹ̀kẹ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún oòrùn.

12. Ó wó o palẹ̀ pẹpẹ tí àwọn ọba Júdà ti wọ́n gbé dúró ní ori òrùlé lẹ́bá yàrá òkè ti Áhásì pẹ̀lú àwọn pẹpẹ tí Mánásè ti kọ́ nínú ilé ẹjọ́ méjèèjì sí ilé Olúwa. Ó sí wọn kúrò níbẹ̀, ó fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Ó sì da ekuru wọn sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì.

13. Ọba pẹ̀lú ba ohun mímọ́ àwọn ibi gíga jẹ́ tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Jérúsálẹ́mù ní ìhà gúṣù ti òkè ìbàjẹ́—èyí tí Ṣólómónì ọba Ísírẹ́lì ti kọ́ fún Ásítórétì ọlọ́run ìríra àwọn ará Ṣídónì, fún Kémóṣì ọlọ́run ìríra àwọn ará Móábù àti fún Mólékì, ọlọ́run ìríra àwọn ènìyàn Ámónì.

14. Jòṣíàh fọ́ òkúta yíyà sọ́tọ̀, ó sì gé òpó Áṣérà lulẹ̀. Ó sì bo ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ ẹ rẹ̀ pẹ̀lú egungun ènìyàn.

15. Àní pẹpẹ tí ó wà ní Bétélì ibi gíga tí Jéróbóámù ọmọ Nébátí dá. Tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti ṣẹ̀—Àní pẹpẹ náà àti ibi gíga tí ó fọ́ túútúú. Ó jó àwọn ibi gíga, ó sì lọ̀ ọ́ sí ẹ̀tù, ó sì ṣun òpó Áṣérà pẹ̀lú.

16. Nígbà náà, Jòṣíà wò yíká, nígbà tí ó sì rí àwọn iṣà òkú tí ó wà níbẹ̀ ní ẹ̀bá òkè, ó yọ egungun kúrò lára wọn, ó sì jó wọn lórí pẹpẹ láti sọ ọ́ di èérí ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí a ti kéde láti ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀.

17. Ọba sì béèrè, pé “Kí ni ọwọ́n iṣà òkú yẹn tí mo rí?”Àwọn ọkùnrin ìlú ńlá wí pé, “Ó sàmì sí iṣà òkú ènìyàn Ọlọ́run tí ó wá láti Júdà, tí ó sì kéde ìdojúkọ pẹpẹ Bétélì, ohun kan wọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe sí wọn.”

18. “Fi sílẹ̀ nìkan,” Ó wí pé. “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó da àwọn egungun rẹ̀ láàmú.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá egungun rẹ̀ sí àti ti àwọn wòlíì tí ó wá láti Ṣamáríà.

19. Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Bétélì, Jòṣíàh sì kúrò, ó sì ba gbogbo ojúbọ òrìṣà ti ibi gíga jẹ́, tí àwọn ọba Ísírẹ́lì ti kọ́ sí àwọn ìlú ní Ṣamáríà, tí ó ti mú Olúwa bínú.

20. Jòṣíáyà dúńbú gbogbo àwọn àlùfáà ibi gíga lórí pẹpẹ. Ó sì ṣun egungun ènìyàn lórí wọn. Nígbà náà, ó padà lọ sí Jérúsálẹ́mù.

21. Ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé: “Ẹ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa Ọlọ́run yín, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sí inú ìwé májẹ̀mú yìí.”

Ka pipe ipin 2 Ọba 23