Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 44:7-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, nitori kini ẹ ṣe da ẹ̀ṣẹ nla yi si ọkàn nyin, lati ke ninu nyin ani ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati ọmọ-ọmu, kuro lãrin Juda, lati má kù iyokú fun nyin;

8. Ninu eyiti ẹnyin fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, ni sisun turari fun ọlọrun miran ni ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin lọ lati ṣatipo, ki ẹ le ke ara nyin kuro, ati ki ẹ le jẹ ẹni-ègun ati ẹsin, lãrin gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye?

9. Ẹnyin ha ti gbagbe ìwa-buburu awọn baba nyin, ati ìwa-buburu awọn ọba Juda, ati ìwa-buburu awọn aya wọn, ati ìwa-buburu ẹnyin tikara nyin, ati ìwa-buburu awọn aya nyin, ti nwọn ti hù ni ilẹ Juda, ati ni ita Jerusalemu.

10. Nwọn kò rẹ̀ ara wọn silẹ titi di oni yi, bẹ̃ni wọn kò bẹ̀ru, tabi ki nwọn ki o rìn ninu ofin mi, tabi ninu ilana mi ti emi gbe kalẹ niwaju nyin ati niwaju awọn baba nyin.

11. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, wò o emi doju mi kọ nyin fun ibi, ati lati ke gbogbo Juda kuro.

12. Emi o si mu gbogbo iyokù Juda, ti o ti gbe oju wọn si ati lọ si ilẹ Egipti, lati ṣatipo nibẹ, gbogbo wọn ni yio si run, nwọn o si ṣubu ni ilẹ Egipti; nwọn o si run nipa idà ati nipa ìyan, nwọn o kú lati ẹni-kekere wọn titi de ẹni-nla wọn, nipa idà, ati nipa ìyan: nwọn o si di ẹni-ègun, ẹni-iyanu, ati ẹni-ẹ̀gan, ati ẹsin.

13. Nitori emi o bẹ̀ awọn ti ngbe Egipti wò, gẹgẹ bi emi ti jẹ Jerusalemu niya, nipa idà, nipa ìyan, ati nipa àjakalẹ-arun;

14. Kì o si si ẹniti o sala, ati ẹniti o kù, fun awọn iyokù Juda, ti o wọ ilẹ Egipti lati ma ṣatipo nibẹ, ti yio pada si ilẹ Juda, si eyiti nwọn ni ifẹ ati pada lọ igbe ibẹ: nitori kò si ọkan ti yio pada bikoṣe iru awọn ti o sala.

15. Nigbana ni gbogbo awọn ọkunrin ti nwọn mọ̀ daju pe, awọn aya wọn ti sun turari fun ọlọrun miran, ati gbogbo awọn obinrin ti o duro nibẹ, apejọ nla, ati gbogbo awọn enia ti ngbe ilẹ Egipti ani ni Patrosi, da Jeremiah lohùn, wipe,

16. Ọ̀rọ ti iwọ sọ fun wa li orukọ Oluwa, awa kì yio feti si tirẹ.

17. Ṣugbọn dajudaju awa o ṣe ohunkohun ti o jade lati ẹnu wa wá, lati sun turari fun ayaba ọrun, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, gẹgẹ bi awa ti ṣe, awa, ati awọn baba wa, awọn ọba wa, ati awọn ijoye wa ni ilu Juda, ati ni ita Jerusalemu: nigbana awa ni onjẹ pupọ, a si ṣe rere, a kò si ri ibi.

18. Ṣugbọn lati igba ti awa ti fi sisun turari fun ayaba ọrun silẹ, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, awa ti ṣalaini ohun gbogbo, a si run nipa idà ati nipa ìyan.

19. Ati nigbati awa sun turari fun ayaba ọrun ti a si da ẹbọ ohun mimu fun u, lẹhin awọn ọkọ wa ni awa ha dín akara didùn rẹ̀ lati bọ ọ, ti a si da ẹbọ ohun mimu fun u bi?

20. Nigbana ni Jeremiah sọ fun gbogbo awọn enia, fun awọn ọkunrin, ati fun awọn obinrin, ati fun gbogbo awọn enia ti o ti fun u li èsi yi wipe.

21. Turari ti ẹnyin sun ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu, ẹnyin ati awọn baba nyin, awọn ọba nyin, ati awọn ijoye nyin, ati awọn enia ilẹ na, Oluwa kò ha ranti rẹ̀, kò ha si wá si ọkàn rẹ̀?

22. Tobẹ̃ ti Oluwa kò le rọju pẹ mọ, nitori buburu iṣe nyin, ati nitori ohun irira ti ẹnyin ti ṣe; bẹ̃ni ilẹ nyin di ahoro, ati iyanu ati ègun, laini olugbe, bi o ti ri li oni yi.

23. Nitori ti ẹnyin ti sun turari, ati nitori ti ẹnyin ṣẹ̀ si Oluwa, ti ẹnyin kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, ti ẹ kò rin ninu ofin rẹ̀, ati ninu ilana rẹ̀, ati ninu ọ̀rọ ẹri rẹ̀; nitorina ni ibi yi ṣe de si nyin, bi o ti ri li oni yi.

24. Jeremiah sọ pẹlu fun gbogbo awọn enia, ati fun gbogbo awọn obinrin na pe, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa gbogbo Juda ti o wà ni ilẹ Egipti:

25. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli sọ, wipe, Ẹnyin ati awọn aya nyin, ẹnyin fi ẹnu nyin sọ̀rọ, ẹ si fi ọwọ nyin mu ṣẹ, ẹ si wipe, lõtọ awa o san ẹ̀jẹ́ wa ti awa ti jẹ, lati sun turari fun ayaba ọrun, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, njẹ ni pipamọ, ẹ pa ẹ̀jẹ́ nyin mọ, ati ni sisan ẹ san ẹ̀jẹ́ nyin.

Ka pipe ipin Jer 44