Nwọn kò rẹ̀ ara wọn silẹ titi di oni yi, bẹ̃ni wọn kò bẹ̀ru, tabi ki nwọn ki o rìn ninu ofin mi, tabi ninu ilana mi ti emi gbe kalẹ niwaju nyin ati niwaju awọn baba nyin.