A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Gébà dé Rímónì lápá gúsù Jérúsálẹ́mù: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jérúsálẹ́mù ṣókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Bẹ́ńjámínì títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ile ìṣọ́ Hánánélì dé ibi ìfúńtí wáìnì ọba.