Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 40:30-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. (Àwọn àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tí ó yí àgbàlá po jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹẹdọ́gbọ̀n ni fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni jínjìn).

31. Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ tí ó dojúkọ àgbàlá tí ìta, igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀sọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó lọ sì òkè sí i.

32. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí àgbàlá tí inú ni ìhà ilà òòrùn, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù.

33. Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu ọ̀nà náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ni ihò yí po. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀.

34. Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ àgbàlá tí ìta; àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀sọ́ sí àtẹ́rígbà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ sì lọ sókè rẹ̀.

35. Gẹ́gẹ́ bí àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀ ṣe rí. Àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, ó sì ní àwọn ihò yí i po. O jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dọgbọ̀n ní fífẹ̀.

36. Àwọn yàrá ẹ̀sọ́ rẹ̀ àwọn òpó rẹ̀ àti ìloro rẹ̀, àti fèrèsé rẹ̀ yíká: gígùn rẹ̀ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àti ìbú rẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ mẹẹdọ́gbọ̀n.

37. Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ àgbàlá ìta; àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀sọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó so mọ́ ọn lókè.

38. Yàrá kan pẹ̀lú ilẹ̀kùn wà ní ẹ̀gbẹ́ àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ní ọ̀kọ́ọ́kan ẹnu ọ̀nà inú, níbi tí wọn tí ń fọ àwọn ẹbọ sísun.

39. Ní àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tí ẹnu ọ̀nà ni tẹ́ḿpìlì méjì wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan, lórí èyí tí a ti ń pá ọrẹ ẹbọ sísun, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.

40. Ní ẹ̀gbẹ́ ògiri ìta àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà tí ẹnu ọ̀nà, tí ó súnmọ́ àwọn àtẹ̀gùn ní àbáwọlé tí ẹnu ọ̀nà àríwá ni tẹ́ḿpìlì méjì wà, ní ẹ̀gbẹ́ kejì tí àtẹ̀gùn ní tẹ́ḿpìlì méjì wà.

41. Nítorí náà, tẹ́ḿpìlì mẹ́rin ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan ẹnu ọ̀nà, mẹ́rin sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì tẹ́ḿpìlì, mẹ́jọ ni gbogbo rẹ̀ lórí èyí ni a ti ń pa ohun ìrúbọ.

42. Tẹ́ḿpìlì mẹ́rin tí à fi òkúta ṣe lọ́sọ̀ọ́ sì tún wà fún ẹbọ sísun, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ni gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ kan ni gíga. Ní orí rẹ̀ ni a kó àwọn ohun èlò fún pípa, ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ìrubọ tí ó kù sí.

43. Ìlọ́po méjì ohun èlò bí àmúga tí o ní ìwọ̀ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìbú ọwọ́ ní gígùn, ni a so mọ́ ara ògiri yíká. Àwọn tẹ́ḿpìlì náà wa fún ẹran ohun ìrúbọ.

44. Lẹ́yìn náà ó wọn àgbàlá: Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ. Pẹpẹ sì wà ní iwájú tẹ́ḿpìlì.

45. Ó sì wí fún mi pé, “yàrá yìí, tí iwájú rẹ̀ wà níhà gúsù, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti n bojútó ilé náà.

46. Iyàrá ti iwájú rẹ̀ ti o wà níhà àríwá, wà fún àwọn àlúfáà, àwọn ti ń bojútó pẹpẹ náà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Sádókù nínú àwọn ọmọ Léfì, tí wọ́n ń súnmọ́ Olúwa láti ṣe ìránṣẹ́ fún un.”

47. Ó sì wọn àgbàlá náà, ọgọ́rùn ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọgọ́rùn ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú, igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, àti pẹpẹ ti ń bẹ níwájú ilé náà.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 40