Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ísíkẹ́lì 40:23-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ẹnu ọ̀nà kan sí àgbàlá ti inú ni àdojúkọ ẹnu ọ̀nà àríwá, gẹ́gẹ́ bí o ṣe wà ní ìlà òòrùn. Ó wọ̀n láti ẹnu ọ̀nà sí àdojúkọ ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

24. Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí ìhà gúsù, mo sì rí ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ gúsù. Ó wọn àtẹ́rígbà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ bákan náà bí ti àwọn tí o kù.

25. Ẹnu ọ̀nà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ni ojú ihò tóóró yí po, gẹ́gẹ́ bí ojú ihò ti àwọn tókù. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ní fífẹ̀.

26. Àtẹ̀gùn méje ní ó dé ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ní òdì kejì wọn; Ó ní igi ọ̀pẹ tí a fi ṣe ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ni ojú ìgbéró ògiri ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan.

27. Àgbàlá ti inú náà ní ẹnu ọ̀nà yìí sí ẹnu ọ̀nà ìta ni ìhà gúsù; Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

28. Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí àgbàlá ti inú láti ẹnu ọ̀nà gúsù, ó ní ìwọ̀n kan náà ẹnu ọ̀nà gúsù; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù.

29. Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ bákan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu ọ̀nà náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ní ihò ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gbogbo

30. (Àwọn àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tí ó yí àgbàlá po jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹẹdọ́gbọ̀n ni fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni jínjìn).

31. Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ tí ó dojúkọ àgbàlá tí ìta, igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀sọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó lọ sì òkè sí i.

32. Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí àgbàlá tí inú ni ìhà ilà òòrùn, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù.

33. Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu ọ̀nà náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ni ihò yí po. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀.

34. Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ àgbàlá tí ìta; àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀sọ́ sí àtẹ́rígbà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ sì lọ sókè rẹ̀.

35. Gẹ́gẹ́ bí àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀ ṣe rí. Àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, ó sì ní àwọn ihò yí i po. O jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dọgbọ̀n ní fífẹ̀.

36. Àwọn yàrá ẹ̀sọ́ rẹ̀ àwọn òpó rẹ̀ àti ìloro rẹ̀, àti fèrèsé rẹ̀ yíká: gígùn rẹ̀ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àti ìbú rẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ mẹẹdọ́gbọ̀n.

37. Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ àgbàlá ìta; àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀sọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó so mọ́ ọn lókè.

38. Yàrá kan pẹ̀lú ilẹ̀kùn wà ní ẹ̀gbẹ́ àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ní ọ̀kọ́ọ́kan ẹnu ọ̀nà inú, níbi tí wọn tí ń fọ àwọn ẹbọ sísun.

39. Ní àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tí ẹnu ọ̀nà ni tẹ́ḿpìlì méjì wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan, lórí èyí tí a ti ń pá ọrẹ ẹbọ sísun, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.

40. Ní ẹ̀gbẹ́ ògiri ìta àtẹ̀wọ́ ẹnu ọ̀nà tí ẹnu ọ̀nà, tí ó súnmọ́ àwọn àtẹ̀gùn ní àbáwọlé tí ẹnu ọ̀nà àríwá ni tẹ́ḿpìlì méjì wà, ní ẹ̀gbẹ́ kejì tí àtẹ̀gùn ní tẹ́ḿpìlì méjì wà.

41. Nítorí náà, tẹ́ḿpìlì mẹ́rin ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan ẹnu ọ̀nà, mẹ́rin sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì tẹ́ḿpìlì, mẹ́jọ ni gbogbo rẹ̀ lórí èyí ni a ti ń pa ohun ìrúbọ.

Ka pipe ipin Ísíkẹ́lì 40