Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 59:8-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀;kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọnwọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ́rọ,kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.

9. Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa,àti tí òdodo kò fi tẹ̀wá lọ́wọ́.A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ jẹ́ òkùnkùn;fún ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.

10. Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògirití a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú.Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni;láàrin alágbára àwa dàbí òkú.

11. Gbogbo wa là ń ké bí i bíárì;àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbàA ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ̀nàfún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.

12. Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ,àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá.Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa,àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,

13. ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa,kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run,dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀,pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbérò síta.

14. Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo ṣẹ́yìn,àti ti òdodo dúró lókèèrè;òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà,òdodo kò sì le è wọlé.

15. A kò rí òtítọ́ mọ́,àti ẹni tí ó bá sá ibi tì di ìjẹ. Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́pé kò sí ìdájọ́ òdodo.

16. Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;nítorí apá òun tìkálárarẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,àti òdodo òun tìkálára rẹ̀ ló gbé e ró.

17. Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàya rẹ̀,àti àsíborí ìgbàlà ní oríi rẹ̀;ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.

18. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe,bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣan ánìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;òun yóò ṣan án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.

19. Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,àti láti ìlà oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀.Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omièyí tí èémí Olúwa ń tì lọ.

Ka pipe ipin Àìsáyà 59