Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 30:18-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Nitorina ni Oluwa yio duro, ki o le ṣe ore fun nyin, ati nitori eyi li o ṣe ga, ki o le ṣe iyọ́nu si nyin: nitori Oluwa li Ọlọrun idajọ: ibukun ni fun gbogbo awọn ti o duro dè e.

19. Nitori awọn enia Sioni yio gbe Jerusalemu, iwọ kì yio sọkun mọ: yio ṣanu fun ọ gidigidi nigbati iwọ ba nkigbe; nigbati on ba gbọ́ ọ, yio dá ọ lohùn.

20. Oluwa yio si fi onjẹ ipọnju, ati omi inira fun nyin, awọn olukọ́ni rẹ kì yio sápamọ́ mọ, ṣugbọn oju rẹ yio ri olukọ́ni rẹ̀:

21. Eti rẹ o si gbọ́ ọ̀rọ kan lẹhin rẹ, wipe, Eyiyi li ọ̀na, ẹ ma rin ninu rẹ̀, nigbati ẹnyin bá yi si apa ọtún, tabi nigbati ẹnyin bá yi si apa òsi.

22. Ẹnyin o si sọ ibora ere fadaka nyin wọnni di aimọ́, ati ọṣọ́ ere wura didà nyin wọnni: iwọ o sọ wọn nù bi ohun-aimọ́, iwọ o si wi fun u pe, Kuro nihinyi.

23. On o si rọ̀ òjo si irugbin rẹ ti iwọ ti fọ́n si ilẹ: ati onjẹ ibísi ilẹ, yio li ọrá yio si pọ̀: li ọjọ na ni awọn ẹran rẹ yio ma jẹ̀ ni pápa oko nla.

24. Awọn akọ-malu pẹlu, ati awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ ti ntulẹ yio jẹ oko didùn, ti a ti fi kọ̀nkọsọ ati atẹ fẹ.

25. Ati lori gbogbo oke-nla giga, ati lori gbogbo oke kékèké ti o ga, ni odò ati ipa-omi yio wà li ọjọ pipa nla, nigbati ile-iṣọ́ wọnni bá wó.

26. Imọ́lẹ oṣupa yio si dabi imọ́lẹ õrun, imọ́lẹ õrun yio si ràn ni iwọ̀n igbà meje, bi imọ́lẹ ọjọ meje, li ọjọ ti Oluwa dí yiya awọn enia rẹ̀, ti o si ṣe àwotán ọgbẹ ti a ṣá wọn.

27. Kiyesi i, orukọ Ọluwa mbọ̀ lati ọ̀na jijin wá, ibinu rẹ̀ si njo, ẹrù rẹ̀ si wuwo: ète rẹ̀ si kún fun ikannu, ati ahọn rẹ̀ bi ajonirun iná:

28. Ẽmi rẹ̀ bi kikun omi, yio si de ãrin-meji ọrùn, lati fi kọ̀nkọsọ kù awọn orilẹ-ède: ijanu yio si wà li ẹ̀rẹkẹ́ awọn enia, lati mu wọn ṣina.

29. Ẹnyin o li orin kan, gẹgẹ bi igbati a nṣe ajọ li oru; ati didùn inu, bi igbati ẹnikan fun fère lọ, lati wá si òke-nla Oluwa, sọdọ Apata Israeli.

Ka pipe ipin Isa 30