Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 8:23-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. O si wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ loke ọrun, tabi ni isalẹ ilẹ, ti ipa majẹmu ati ãnu mọ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ ti nfi gbogbo ọkàn wọn rin niwaju rẹ:

24. Ẹniti o ti ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa ohun ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ: iwọ fi ẹnu rẹ sọ pẹlu, o si ti fi ọwọ́ rẹ mu u ṣẹ, gẹgẹ bi o ti ri loni.

25. Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun Israeli, ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa ohun ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́ wipe, A kì yio fẹ ọkunrin kan kù li oju mi lati joko lori itẹ Israeli; kiki bi awọn ọmọ rẹ ba le kiyesi ọ̀na wọn, ki nwọn ki o mã rìn niwaju mi gẹgẹ bi iwọ ti rìn niwaju mi.

26. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun Israeli, jẹ ki a mu ọ̀rọ rẹ ṣẹ, emi bẹ̀ ọ, ti iwọ ti sọ fun iranṣẹ rẹ, Dafidi baba mi.

27. Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun yio ha mã gbe aiye bi? wò o, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọ̀sì ile yi ti mo kọ́?

28. Sibẹ̀ iwọ ṣe afiyèsi adura iranṣẹ rẹ, ati si ẹbẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati si adura, ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ loni:

29. Ki oju rẹ lè ṣi si ile yi li ọsan ati li oru, ani si ibi ti iwọ ti wipe: Orukọ mi yio wà nibẹ: ki iwọ ki o lè tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ yio gbà si ibi yi.

30. Ki o si tẹtisilẹ si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ ati ti Israeli, enia rẹ, ti nwọn o gbadura siha ibi yi: ki o si gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ! gbọ́, ki o si darijì.

31. Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, bi ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi:

32. Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni didẹbi fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ wá si ori rẹ̀; ati ni didare fun olõtọ, lati fun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀.

33. Nigbati a ba lù Israeli, enia rẹ bòlẹ niwaju awọn ọ̀ta, nitoriti nwọn dẹṣẹ si ọ, ti nwọn ba si yipada si ọ, ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn si gbadura, ti nwọn si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ ni ile yi:

34. Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ Israeli, enia rẹ jì, ki o si mu wọn pada wá si ilẹ ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn.

35. Nigbati a ba sé ọrun mọ, ti kò si òjo, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si ọ: bi nwọn ba gbadura si iha ibi yi, ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, bi nwọn ba si yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn, nigbati iwọ ba pọ́n wọn li oju.

36. Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jì, ati ti Israeli, enia rẹ, nigbati o kọ́ wọn li ọ̀na rere ninu eyiti nwọn iba mã rin, ki o si rọ̀ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun enia rẹ ni ilẹ-ini.

37. Bi iyàn ba mu ni ilẹ, bi ajakalẹ-arùn ni, tabi ìrẹdanu, tabi bibu, tabi bi ẽṣu tabi bi kòkorò ti njẹrun ba wà; bi ọtá wọn ba dó tì wọn ni ilẹ ilu wọn; ajakalẹ-arùn gbogbo, arùn-ki-arun gbogbo.

38. Adura ki adura, ati ẹ̀bẹ ki ẹ̀bẹ, ti a ba ti ọdọ ẹnikan tabi lati ọdọ gbogbo Israeli, enia rẹ gbà, ti olukuluku yio mọ̀ ibanujẹ ọkàn ara rẹ̀, bi o ba si tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mejeji si iha ile yi!

39. Nigbana ni ki iwọ ki o gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ, ki o si darijì, ki o si ṣe ki o si fun olukulùku enia gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ọkàn ẹniti iwọ mọ̀; nitoriti iwọ, iwọ nikanṣoṣo li o mọ̀ ọkàn gbogbo awọn ọmọ enia;

40. Ki nwọn ki o lè mã bẹ̀ru rẹ ni gbogbo ọjọ ti nwọn wà ni ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa.

41. Pẹlupẹlu, niti alejò, ti kì iṣe ti inu Israeli enia rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ okerè jade wá nitori orukọ rẹ.

42. Nitoriti nwọn o gbọ́ orukọ nla rẹ, ati ọwọ́ agbára rẹ, ati ninà apa rẹ; nigbati on o wá, ti yio si gbadura si iha ile yi;

43. Iwọ gbọ́ li ọrun, ibùgbe rẹ, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejò na yio ke pè ọ si: ki gbogbo aiye ki o lè mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o lè mã bẹ̀ru rẹ, gẹgẹ bi Israeli, enia rẹ, ki nwọn ki o si lè mọ̀ pe: orukọ rẹ li a fi npè ile yi ti mo kọ́.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 8