Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luku 10:23-42 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ẹ ṣe oríire tí ojú yín rí àwọn ohun tí ẹ rí,

24. nítorí mò ń sọ fun yín pé ọ̀pọ̀ àwọn wolii ati àwọn ọba ni wọ́n fẹ́ rí àwọn nǹkan tí ẹ rí, ṣugbọn tí wọn kò rí i; wọ́n fẹ́ gbọ́ ohun tí ẹ gbọ́ ṣugbọn wọn kò gbọ́ ọ.”

25. Amòfin kan wá, ó fi ìbéèrè yìí wá Jesu lẹ́nu wò. Ó ní, “Olùkọ́ni, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”

26. Jesu bi í pé, “Kí ni ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin? Báwo ni o ti túmọ̀ rẹ̀?”

27. Ó dáhùn pé, “Kí ìwọ fẹ́ràn Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati pẹlu gbogbo agbára rẹ ati pẹlu gbogbo òye rẹ; sì fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí ara rẹ.”

28. Jesu sọ fún un pé, “O wí ire. Máa ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóo sì yè.”

29. Ṣugbọn amòfin náà fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ó wá bi Jesu pé, “Ta ni ọmọnikeji mi?”

30. Jesu bá dá a lóhùn pé, “Ọkunrin kan ń ti Jerusalẹmu lọ sí Jẹriko, ni ó bá bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà. Wọ́n gba aṣọ lára rẹ̀, wọ́n lù ú, wọ́n bá fi í sílẹ̀ nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ kú tán.

31. Alufaa kan tí ó ń bọ̀ ṣe kòńgẹ́ rẹ̀ ní ọ̀nà, ṣugbọn nígbà tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ.

32. Bákan náà ni ọmọ Lefi kan. Nígbà tí òun náà dé ibẹ̀, tí ó rí i, ó gba òdìkejì kọjá lọ.

33. Ṣugbọn ará Samaria kan tí ó ń gba ọ̀nà yìí kọjá lọ dé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà. Nígbà tí ó rí i, àánú ṣe é.

34. Ó bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó fi òróró ati ọtí waini sí ojú ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ wé e. Ó gbé ọkunrin náà ka orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ó gùn. Ó gbé e lọ sí ilé èrò níbi tí ó ti ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

35. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó yọ owó fadaka meji jáde, ó fún olùtọ́jú ilé èrò, ó ní, ‘Ṣe ìtọ́jú ọkunrin yìí. Ohun tí o bá ná lé e lórí, n óo san án fún ọ nígbà tí mo bá pada dé.’

36. “Ninu àwọn mẹta yìí, ta ni o rò pé ó jẹ́ ọmọnikeji ẹni tí ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”

37. Amòfin náà dáhùn pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.”Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ náà lọ ṣe bẹ́ẹ̀ gan-an.”

38. Bí wọ́n ti ń lọ ninu ìrìn àjò wọn, Jesu wọ inú abúlé kan. Obinrin kan tí ń jẹ́ Mata bá gbà á lálejò.

39. Mata ní arabinrin kan tí ó ń jẹ́ Maria. Maria yìí jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

40. Ṣugbọn Mata kò rójú nítorí aájò tí ó ń ṣe nípa oúnjẹ. Ni Mata bá wá, ó ní, “Alàgbà, arabinrin mi fi èmi nìkan sílẹ̀ láti máa tọ́jú oúnjẹ, o sì dákẹ́ ò ń wò ó níran! Sọ fún un kí ó wá ràn mí lọ́wọ́.”

41. Ṣugbọn Oluwa dá a lóhùn pé, “Mata! Mata! Ò ń ṣe aájò, o sì ń dààmú nípa ohun pupọ.

42. Ṣugbọn ẹyọ nǹkankan ni ó jẹ́ koṣeemani. Maria ti yan ipò tí ó dára tí a kò ní gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”

Ka pipe ipin Luku 10