Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 25:2-13 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ọkunrin kan wà ní ìlú Maoni tí ń ṣe òwò ní Kamẹli. Ọkunrin náà ní ọrọ̀ lọpọlọpọ; ó ní ẹgbẹẹdogun aguntan (3,000) ati ẹgbẹrun (1,000) ewúrẹ́, Kamẹli níí ti máa ń gé irun aguntan rẹ̀.

3. Orúkọ ọkunrin náà ni Nabali, iyawo rẹ̀ sì ń jẹ́ Abigaili. Obinrin náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n ati arẹwà, ṣugbọn ọkọ rẹ̀ jẹ́ òǹrorò ati eniyan burúkú. Ìdílé Kalebu ni ìdílé rẹ̀.

4. Dafidi gbọ́ ninu aṣálẹ̀ pé Nabali ń gé irun aguntan rẹ̀,

5. ó bá rán ọdọmọkunrin mẹ́wàá lọ sí Kamẹli láti lọ rí Nabali, kí wọ́n sì kí i ní orúkọ òun.

6. Ó ní kí wọ́n kí i báyìí pé, “Alaafia fún ọ, ati fún ilé rẹ ati fún gbogbo ohun tí o ní.

7. Mo gbọ́ pé ò ń gé irun àwọn aguntan rẹ, mo sì fẹ́ kí o mọ̀ pé àwọn olùṣọ́ aguntan rẹ wà lọ́dọ̀ wa fún ìgbà pípẹ́, n kò sì ṣe wọ́n ní ibi kankan. Kò sí ohun tí ó jẹ́ tiwọn tí ó sọnù ní gbogbo ìgbà tí wọ́n wà ní Kamẹli.

8. Bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọdọmọkunrin rẹ, wọn yóo sì sọ fún ọ. Ọjọ́ ọdún ni ọjọ́ òní, nítorí náà jẹ́ kí àwọn ọmọkunrin yìí rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ. Jọ̀wọ́ mú ohunkohun tí ó bá wà ní àrọ́wọ́tó rẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ, ati fún èmi Dafidi, ọmọ rẹ.”

9. Nígbà tí àwọn tí Dafidi rán dé ibẹ̀, wọ́n jíṣẹ́ fún Nabali, ní orúkọ Dafidi, wọ́n sì dúró.

10. Nabali dá àwọn iranṣẹ náà lóhùn pé, “Ta ni Dafidi? Ta ni ọmọ Jese? Ọpọlọpọ iranṣẹ ni ó wà nisinsinyii tí wọn ń sá kúrò ní ọ̀dọ̀ oluwa wọn.

11. Ṣé kí n wá mú oúnjẹ mi ati omi mi ati ẹran tí mo pa fún àwọn tí wọn ń gé irun aguntan mi, kí n sì gbé e fún àwọn tí n kò mọ ibi tí wọ́n ti wá?”

12. Àwọn ọdọmọkunrin náà bá pada lọ sọ gbogbo ohun tí Nabali sọ fún wọn fún Dafidi.

13. Dafidi sì pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sán idà yín mọ́ ìdí.” Gbogbo wọn sì ṣe bí ó ti wí; òun pàápàá sì sán idà tirẹ̀ náà mọ́ ìdí. Irinwo ninu àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ bá a lọ; igba (200) sì dúró ti ẹrù wọn.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 25