Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 14:13-31 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Obinrin náà wí pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe ohun tí ó burú yìí sí àwọn eniyan Ọlọrun? Ọ̀rọ̀ tí o sọ tán nisinsinyii, ara rẹ gan-an ni o fi dá lẹ́bi, nítorí pé, o kò jẹ́ kí ọmọ rẹ pada wá sílé láti ibi tí ó sá lọ?

14. Dájúdájú, gbogbo wa ni a óo kú. A dàbí omi tí ó dà sílẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò sì lè kójọ mọ́. Ẹni tí ó bá ti kú, Ọlọrun pàápàá kì í tún gbé e dìde mọ́, ṣugbọn kabiyesi lè wá ọ̀nà, láti fi mú ẹni tí ó bá sá jáde kúrò ní ìlú pada wálé.

15. Kabiyesi, ìdí tí mo fi kó ọ̀rọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá ni pé, àwọn eniyan ń dẹ́rùbà mí, èyí ni ó mú kí n rò ninu ara mi pé, n óo wá bá ọ sọ̀rọ̀, mo sì ní ìrètí pé, kabiyesi yóo ṣe ohun tí mo wá bẹ̀bẹ̀ pé kí ó bá mi ṣe.

16. Mo mọ̀ pé ọba yóo fetí sílẹ̀ láti gbọ́ tèmi, yóo sì gbà mí kalẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ pa èmi ati ọmọ mi, tí ó sì fẹ́ pa wá run kúrò lórí ilẹ̀ tí Ọlọrun fún àwọn eniyan rẹ̀.

17. Mo sì ti mọ̀ lọ́kàn ara mi pé, ọ̀rọ̀ tí kabiyesi bá sọ fún mi yóo fi mí lọ́kàn balẹ̀ nítorí pé, ọba dàbí angẹli Ọlọrun tí ó mọ ìyàtọ̀ láàrin ire ati ibi. OLUWA Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.”

18. Ọba dá obinrin náà lóhùn pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, mo sì fẹ́ kí o sọ òtítọ́ rẹ̀ fún mi.”Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bèèrè ohunkohun tí o bá fẹ́.”

19. Ọba bá bí i pé, “Ṣé Joabu ni ó rán ọ ní gbogbo iṣẹ́ tí o wá jẹ́ yìí, àbí òun kọ?”Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bí o ti bèèrè ìbéèrè yìí kò jẹ́ kí n mọ̀ bí mo ti lè yí ẹnu pada rárá. Òtítọ́ ni, Joabu ni ó kọ́ mi ní gbogbo ohun tí mo sọ, ati gbogbo bí mo ti ṣe.

20. Ṣugbọn, òun náà fẹ́ tún nǹkan ṣe, ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe. Ṣugbọn kabiyesi ní ọgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run, láti mọ ohun gbogbo lórí ilẹ̀ ayé.”

21. Nígbà náà ni ọba sọ fún Joabu pé, “Mo ti pinnu láti ṣe ohun tí o fẹ́ kí n ṣe. Lọ, kí o sì mú Absalomu, ọmọ mi, pada wá.”

22. Joabu bá wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ọba, ó ní, “Kabiyesi, nisinsinyii ni èmi iranṣẹ rẹ mọ̀ pé mo ti bá ojurere rẹ pàdé, nítorí pé o ṣe ohun tí mo fẹ́.”

23. Joabu bá gbéra, ó lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu pada wá sí Jerusalẹmu.

24. Ṣugbọn ọba pàṣẹ pé kí Absalomu máa gbé ilé rẹ̀, nítorí pé òun kò fẹ́ rí i sójú. Nítorí náà, inú ilé Absalomu ni ó ń gbé, kò sì dé ọ̀dọ̀ ọba rárá.

25. Kò sí ẹyọ ẹnìkan ní gbogbo Israẹli tí òkìkí ẹwà rẹ̀ kàn bí ti Absalomu. Kò sí àbùkù kankan rárá lára rẹ̀ bí ti í wù kó mọ, láti orí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.

26. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni í máa ń gé irun orí rẹ̀, nígbà tí ó bá kún, tí ó sì gùn ju bí ó ti yẹ lọ. Tí wọ́n bá fi ìwọ̀n ọba wọn èyí tí wọ́n bá gé lára irun rẹ̀, a máa tó igba ṣekeli.

27. Absalomu bí ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin kan. Tamari ni orúkọ ọmọbinrin yìí, ó sì jẹ́ arẹwà.

28. Ọdún meji ni Absalomu fi gbé Jerusalẹmu láì fi ojú kan ọba.

29. Ní ọjọ́ kan, ó ranṣẹ sí Joabu, pé kí ó wá mú òun lọ sọ́dọ̀ ọba, ṣugbọn Joabu kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Absalomu ranṣẹ pe Joabu lẹẹkeji, Joabu sì tún kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

30. Absalomu bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Oko Joabu wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tèmi, ó sì gbin ọkà baali sinu rẹ̀, ẹ lọ fi iná sí oko náà.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ti iná bọ oko Joabu.

31. Nígbà náà ni Joabu lọ sí ilé Absalomu, ó bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn iranṣẹ rẹ fi ti iná bọ oko mi?”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 14