Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 50:6-24 BIBELI MIMỌ (BM)

6. “Àwọn eniyan mi dàbí aguntan tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́ wọn ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ń lọ síhìn-ín, sọ́hùn-ún lórí òkè, wọ́n ń ti orí òkè kéékèèké bọ́ sí orí òkè ńláńlá; wọ́n ti gbàgbé ọ̀nà agbo wọn.

7. Gbogbo àwọn tí wọn rí wọn ń pa wọ́n jẹ, àwọn ọ̀tá wọn sì ń wí pé, ‘A kò ní ẹ̀bi kankan, nítorí pé wọ́n ti ṣẹ OLÚWA, tí ó jẹ́ ibùgbé òdodo wọn, ati ìrètí àwọn baba wọn.’

8. “Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni, ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, bí òbúkọ tí ó ṣáájú agbo ẹran.

9. Nítorí n óo rú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè sókè, láti ìhà àríwá, n óo sì kó wọn wá, wọn óo wá dóti Babiloni, wọn yóo gbógun tì í. Ibẹ̀ ni ọwọ́ wọn yóo ti tẹ̀ ẹ́, tí wọn óo sì fogun kó o. Ọfà wọn dàbí akọni ọmọ ogun, tí kì í pada sílé lọ́wọ́ òfo.

10. Ohun ìní àwọn ará Kalidea yóo di ìkógun; gbogbo àwọn tí wọn yóo kó wọn lẹ́rù ni yóo kó ẹrù ní àkótẹ́rùn, Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

11. OLUWA ní, “Ẹ̀yin ará Babiloni, tí ẹ kó àwọn eniyan mi,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú yín dùn ẹ sì ń yọ̀,tí ẹ sì ń ṣe ojúkòkòrò, bí akọ mààlúù tí ń jẹko ninu pápá,tí ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin:

12. Ojú yóo ti olú-ìlú yín lọpọlọpọ,a óo dójú ti ilẹ̀ ìbí yín.Wò ó! Yóo di èrò ẹ̀yìn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,yóo di aṣálẹ̀ tí ó gbẹ.

13. Nítorí ibinu gbígbóná OLUWA,ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́;yóo di ahoro patapata;ẹnu yóo ya gbogbo ẹni tí ó bá gba Babiloni kọjá,wọn yóo sì máa pòṣé nítorí ìyà tí a fi jẹ ẹ́.

14. “Ẹ gbógun ti Babiloni yíká, gbogbo ẹ̀yin tafàtafà. Ẹ máa ta á lọ́fà, ẹ má ṣẹ́ ọfà kankan kù, nítorí pé ó ti ṣẹ OLUWA.

15. Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká, ẹ hó bò ó, ó ti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn ibi ààbò rẹ̀ ti wó, àwọn odi rẹ̀ sì ti wó lulẹ̀. Nítorí ẹ̀san OLUWA ni, ẹ gbẹ̀san lára rẹ̀; ẹ ṣe sí i bí òun náà ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.

16. Ẹ pa àwọn afunrugbin run ní Babiloni, ati àwọn tí ń lo dòjé ní ìgbà ìkórè. Olukuluku yóo pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, yóo sì sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀, nítorí idà àwọn aninilára.”

17. OLUWA ní, “Israẹli dàbí aguntan tí àwọn kinniun ń lé kiri. Ọba Asiria ni ó kọ́kọ́ fi ṣe ẹran ìjẹ, ọba Babiloni sì ń wó àwọn egungun rẹ̀ tí ó kù.

18. Nítorí náà èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ ọba Babiloni ati ilẹ̀ rẹ̀ níyà, bí mo ṣe jẹ ọba Asiria níyà.

19. N óo mú Israẹli pada sí ibùjẹ rẹ̀, yóo máa jẹ oúnjẹ tí ó bá hù lórí òkè Kamẹli ati ní agbègbè Baṣani, yóo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn lórí òkè Efuraimu ati òkè Gileadi.

20. OLUWA ní, Nígbà tí ó bá yá, tí àkókò bá tó, a óo wá ẹ̀ṣẹ̀ tì ní Israẹli ati Juda; nítorí pé n óo dáríjì àwọn tí mo bá ṣẹ́kù.”

21. OLUWA ní,“Ẹ gbógun ti ilẹ̀ Merataimu, ati àwọn ará Pekodi.Ẹ pa wọ́n, kí ẹ sì run wọ́n patapata.Gbogbo nǹkan tí mo pàṣẹ fun yín ni kí ẹ ṣe.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

22. A gbọ́ ariwo ogun ati ìparun ńlá, ní ilẹ̀ náà.

23. Ẹ wo bí a ti gé òòlù tó ti ń lu gbogbo ayé lulẹ̀,tí a sì fọ́ ọ!Ẹ wo bí Babiloni ti di ohun àríbẹ̀rù, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

24. Mo dẹ tàkúté sílẹ̀ fun yín, ẹ̀yin ará Babiloni:Tàkúté náà mu yín, ẹ kò sì mọ̀.Wọ́n ri yín, ọwọ́ sì tẹ̀ yín,nítorí pé ẹ yájú sí èmi OLUWA.

Ka pipe ipin Jeremaya 50