Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 33:5-21 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe di ọba ní Jeṣuruni,nígbà tí gbogbo àwọn olórí péjọ,àní, gbogbo àwọn olórí ninu ẹ̀yà Israẹli.

6. Mose súre fún ẹ̀yà Reubẹni, ó ní:“Ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ni, kò ní parun,àwọn eniyan rẹ̀ kò ní dínkù.”

7. Ó súre fún ẹ̀yà Juda pé:“OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀yà Juda,nígbà tí wọ́n bá pè fún ìrànwọ́,sì kó wọn pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wọn.Fi ọwọ́ ara rẹ jà fún wọn,sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ọ̀tá wọn.”

8. Ó súre fún ẹ̀yà Lefi pé:“OLUWA, fún Lefi, ẹni tíí ṣe olódodo, ní Tumimu ati Urimu rẹ;Lefi, tí o dánwò ní Masa,tí o sì bá jà níbi odò tí ó wà ní Meriba;

9. àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn kò ka òbí àwọn sí, ju ìwọ OLUWA lọ;wọ́n kọ àwọn arakunrin wọn sílẹ̀,wọ́n sì ṣá àwọn ọmọ wọn tì.Nítorí pé wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ,wọ́n sì ń pa majẹmu rẹ mọ́.

10. Wọn óo kọ́ ilé Jakọbu ní ìlànà rẹ,wọn óo sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli ní òfin rẹ.Àwọn ni wọn óo máa sun turari níbi ẹbọ rẹ,wọn óo sì máa rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ rẹ.

11. OLUWA, bukun àwọn ohun ìní wọn,sì jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wọn jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lójú rẹ,Fọ́ egungun itan àwọn ọ̀tá wọn,tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́,kí àwọn tí wọ́n bá kórìíra wọn má sì lè gbérí mọ́.”

12. Ó súre fún ẹ̀yà Bẹnjamini pé:“Bẹnjamini, ẹ̀yà tí OLUWA fẹ́ràn tí ó sì ń dáàbò bò,OLUWA ń ṣọ́ wọn nígbà gbogbo,ó sì ń gbé ààrin wọn.”

13. Ó súre fún ẹ̀yà Josẹfu pé:“Kí OLUWA rọ òjò ibukun sórí ilẹ̀ wọn,kí ó sì bu omi rin ín láti abẹ́ ilẹ̀ wá.

14. Kí OLUWA pèsè ọpọlọpọ èso sórí ilẹ̀ wọn,kí ó sì kún fún àwọn èso tí ó dára jùlọ láti ìgbà dé ìgbà.

15. Kí àwọn òkè ńláńlá àtijọ́ so ọpọlọpọ èso dáradára,kí ọpọlọpọ èso sì bo àwọn òkè kéékèèké.

16. Kí ilẹ̀ wọn kún fún oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ó dára,pẹlu ibukun láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ń gbé inú pápá tí ń jó.Kí ó wá sórí Josẹfu,àní, sórí ẹni tó jẹ́ aṣiwaju fún àwọn arakunrin rẹ̀.

17. Àkọ́bí rẹ̀ lágbára bí akọ mààlúù,Ìwo rẹ̀ sì dàbí ìwo mààlúù tí ó lágbára,tí yóo fi máa ti àwọn orílẹ̀-èdè títí dé òpin ayé.Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹgbẹẹgbaarun àwọn ọmọ Efuraimu,ati ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Manase.”

18. Ó súre fún Sebuluni ati fún Isakari, ó ní:“Máa yọ̀ bí o ti ń jáde lọ, ìwọ Sebuluni,sì máa yọ̀ ninu ilé rẹ, ìwọ Isakari.

19. Wọn óo pe àwọn àlejò jọ sórí òkè,wọn óo sì máa rú ẹbọ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ níbẹ̀.Nítorí wọn óo máa kó ọrọ̀ jọ láti inú òkun,ati dúkìá tí ó farasin láti inú yanrìn etí òkun.”

20. Ìre tí ó sú fún ẹ̀yà Gadi ni pé:“Ibukun ni fún ẹni tí ó bukun ilẹ̀ Gadi,Gadi dàbí kinniun tí ó ba láti fani lápá ya, ati láti géni lórí.

21. Ibi tí ó dára jùlọ ninu ilẹ̀ náà ni wọ́n mú fún ara wọn,nítorí pé ibẹ̀ ni ìpín olórí ogun wà,ó wá sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn eniyan náà,àtòun, àtàwọn eniyan náà sì ń pa àṣẹ OLUWA mọ́,wọn sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo.”

Ka pipe ipin Diutaronomi 33