Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 20:13-32 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Nítorí náà, ẹ kó àwọn aláìníláárí eniyan tí wọn ń hu ìwà ìkà ní Gibea jáde fún wa, kí á sì pa wọ́n, kí á mú ibi kúrò láàrin Israẹli.” Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò gba ohun tí àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Israẹli ń wí.

14. Àwọn ọmọ Bẹnjamini bá kó ara wọn jọ láti gbogbo ìlú ńláńlá, wọ́n wá sí Gibea láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.

15. Àwọn ọmọ ogun tí àwọn ará Bẹnjamini kó jọ ní ọjọ́ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaata (26,000) àwọn ọkunrin tí wọn ń lo idà; láì ka àwọn tí wọn ń gbé Gibea tí àwọn náà kó ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin jọ.

16. Ẹẹdẹgbẹrin (700) akọni ọkunrin tí wọn ń lo ọwọ́ òsì wà láàrin àwọn ọmọ ogun wọnyi. Wọ́n mọ kànnàkànnà ta, tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé wọ́n lè ta á mọ́ fọ́nrán òwú láì tàsé.

17. Láì ka àwọn tí àwọn ará Bẹnjamini náà kó jọ, àwọn ọmọ Israẹli kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) jagunjagun tí wọn ń lo idà jọ.

18. Àwọn ọmọ Israẹli gbéra lọ sí Bẹtẹli, wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun; ẹ̀yà tí yóo kọ́kọ́ gbógun ti ẹ̀yà Bẹnjamini.OLUWA dá wọn lóhùn pé ẹ̀yà Juda ni yóo kọ́kọ́ gbógun tì wọ́n.

19. Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, wọ́n lọ pàgọ́ sí òdìkejì Gibea,

20. wọ́n bá gbógun ti àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini, wọ́n fi ìlú Gibea ṣe ojú ogun wọn.

21. Àwọn ará Bẹnjamini bá jáde sí wọn láti ìlú Gibea, wọ́n sì pa ọ̀kẹ́ kan (20,000) ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ọjọ́ náà.

22. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli mọ́kàn le, wọ́n tún gbógun tì wọ́n, wọ́n sì tún fi ibi tí wọ́n fi ṣe ojú ogun tẹ́lẹ̀ ṣe ojú ogun wọn.

23. Wọ́n bá lọ sọkún níwájú OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n ní, “Ṣé kí á tún gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tí í ṣe àwọn arakunrin wa?”OLUWA dá wọn lóhùn pé kí wọ́n lọ gbógun tì wọ́n.

24. Àwọn ọmọ Israẹli bá tún lọ gbógun ti àwọn ọmọ ogun Bẹnjamini ní ọjọ́ keji.

25. Àwọn ará Bẹnjamini bá tún jáde láti Gibea ní ọjọ́ keji, wọ́n pa ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) eniyan ninu àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń fi idà jà.

26. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá lọ sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó wọ́n sọkún níbẹ̀ níwájú OLUWA, wọ́n gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú OLUWA.

27. Àwọn ọmọ Israẹli tún wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, nítorí pé àpótí majẹmu Ọlọrun wà ní Bẹtẹli ní àkókò náà.

28. Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni ló ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli tún bèèrè pé, “Ṣé kí á tún lọ gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tíí ṣe arakunrin wa àbí kí á dáwọ́ dúró?”OLUWA dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ lọ gbógun tì wọ́n, nítorí pé, lọ́la ni n óo fi wọ́n le yín lọ́wọ́.”

29. Àwọn ọmọ Israẹli bá fi àwọn eniyan pamọ́ ní ibùba, yípo gbogbo Gibea.

30. Àwọn ọmọ Israẹli tún gbógun ti àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ kẹta, wọ́n tò yípo Gibea bíi ti iṣaaju.

31. Àwọn ará Bẹnjamini jáde sí wọn, àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí fi ọgbọ́n tàn wọ́n kúrò ní ìlú; àwọn ará Bẹnjamini tún bẹ̀rẹ̀ sí pa ninu àwọn ọmọ Israẹli bíi ti iṣaaju. Wọ́n pa wọ́n ní ojú òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí Bẹtẹli ati Gibea ati ninu pápá. Àwọn tí wọ́n pa ninu wọ́n tó ọgbọ̀n eniyan.

32. Àwọn ará Bẹnjamini wí fún ara wọn pé, “A tún ti tú wọn ká bíi ti iṣaaju.”Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sá, kí á sì tàn wọ́n kúrò ninu ìlú wọn, kí wọ́n bọ́ sí ojú òpópó.”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 20