Nítorí náà, ẹ kó àwọn aláìníláárí eniyan tí wọn ń hu ìwà ìkà ní Gibea jáde fún wa, kí á sì pa wọ́n, kí á mú ibi kúrò láàrin Israẹli.” Ṣugbọn àwọn ọmọ Bẹnjamini kò gba ohun tí àwọn arakunrin wọn, àwọn ọmọ Israẹli ń wí.