orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má si ṣe ohun tí ó wu ara wa.

2. Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró.

3. Nítorí Kírísítì pàápàá kò ṣe ohun tí ó wu ara rẹ̀, ṣùgbọ́n, bí a ti kọ ọ́ pé: “Àwọn ẹni tí ń tàbùkù rẹ ń tàbùkù mi pẹ̀lú.”

4. Nítorí ohun gbogbo tí a kọ nígbà àtijọ́ ni a kọ láti fi kọ́ wa, kí àwa lè ní ìrètí nípa sùúrù àti ìtùnú èyí tí ó wá láti inú ìwé mímọ́.

5. Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin ní ẹ̀mí ìrẹ́pọ̀ láàrin ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jésù Kírísítì,

6. kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì.

7. Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run.

8. Mo sì wí pé, a rán Kírísítì láti ṣe ìránṣẹ́ àwọn tí se Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀,

9. kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrin àwọn aláìkọlà,Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.”

10. Ó sì tún wí pé,“Ẹ̀yin aláìkọlà, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.”

11. Àti pẹ̀lú,“Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin aláìkọlà;ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.”

12. Àìṣáyà sì tún wí pé,“Gbòngbò Jésè kan ń bọ̀ wá,òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn aláìkọlà;Àwọn aláìkọlà yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”

13. Njẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yín ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrétí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

Pọ́ọ̀lù Wàásù Sí Àwọn Aláìkọlà

14. Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, è pé ní ìmọ̀, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín.

15. Mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fifún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

16. láti jẹ́ ìránsẹ́ Kírísìtì Jésù láàrin àwọn aláìkọlà láti polongo ìyìn rere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúse àlùfáà, kí àwọn aláìkọlà lè jẹ́ ẹbọ-ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí mímọ́ yà sí mímọ́.

17. Nítorí náà, mo ní ìsògo nínú Kírísítì Jésù nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run.

18. Èmi kò sa à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò se èyí tí Kírisítì ti ọwọ́ mi se, ní títọ́ àwọn aláìkọlà sọ́nà láti ṣe ìgbọ́ran sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi:

19. nípa agbára isẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí a se lọ́wọ́ Ẹ̀mi. Mo ti polongo ìyìn rere Kírísítì ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ láti Jérúsálẹ́mù dé ìlú tí a ń pè ní Ílíríkónì.

20. Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìn rere Kírísítì ní ibi gbogbo tí wọn kò tí i gbọ́ nípa rẹ̀, kí èmi kí ó má se máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn.

21. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Àwọn tí kò tí ì sọ òrọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i,yóò sì yé àwọn tí kò tí ì gbọ́ ọ rí.”

22. Ìdí nì yìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó wa bẹ̀ yín wò.

Pọ́ọ̀lù Pinnu Láti Dé Rómù.

23. Ṣùgbọ́n báyìí tí kò tún sí ibòmíràn fún mi mọ́ ní agbègbè yìí, tí èmi sì ti ń pòùngbẹ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láti tọ̀ yín wá,

24. mo gbèrò láti se bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bá lọ sí orílẹ̀ èdè Sípáníà. Èmi yóò bẹ̀ yín wò ní ọ̀nà ìrìnàjò mi, lẹ́yìn tí a bá sì gbádùn ara wa fún ìgbà díẹ̀, ẹ ó kún mi ọ́wọ́ nínú ìrìnàjò mi láti dé ibẹ̀.

25. Ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ń lọ nínú ìrìnàjò sí ìlú Jérúsálẹ́mù láti sé ìránsẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀.

26. Nítorí pé àwọn tí ó wà ní agbégbé Makedóníà àti agbégbé Ákáyà ti kó ẹ̀bùn jọ fún àwọn talákà tí ó wà ní àárín àwọn ènìyàn mímọ́ ní Jérúsálẹ́mù.

27. Pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n ń se èyí, nítorí wọ́n gbà wí pé, wọ́n jẹ́ ajigbésè fún wọn. Nítorí bí ó bá se pé a fi àwọn aláìkọlà se alájọni nínú ohun ẹ̀mí wọn, ajigbèsè sì ni wọn láti fi ohun ti ara ta wọ́n lọ́rẹ.

28. Nítorí náà, nígbà tí mo bá ti se èyí tán tí mo bá sì di ẹ̀dìdì èso náà fún wọn tán, èmi yóò gba ti ọ̀dọ̀ yín bí mo bá ń lọ sí orílẹ̀ èdè Sípáníà.

29. Mo sì mọ̀ pé nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, èmi yóò wà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkùn Kírísítì.

30. Èmí rọ̀ yín, ẹ̀yin ará, nítorí Olúwa wa Jésù Kírísítì, àti nítorí ìfẹ́ Ẹ̀mí, kí ẹ̀yin kí ó kún mi láti bá mi làkàkà nínú àdúrà yín sí Ọlọ́run fùn mi.

31. Kí a lè kó mi yọ kúrò lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Jùdíà àti kí isẹ́ ìránsẹ́ tí mo ní sí Jérúsálẹ́mù le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀.

32. Nítorí náà, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run kí èmi le fi ayọ̀ tọ̀ yín wa, kí pọ̀ pẹ̀lú yín ní ìtura.

33. Kí Ọlọ́run àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.