orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Síṣe Ìgbọ́ran Sí Àwọn Aláṣẹ

1. Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga. Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run li a ti lànà rẹ̀ wá.

2. Nítorí ẹni tí ó bá tàpá sí àṣẹ, ó tàpá sí ìlànà Ọlọ́run; àwọn ẹni tí ó ba sì ń tàpá, yóò gba ẹ̀bi fún ara wọn.

3. Nítorí pé adájọ́ kò wá láti dẹ́rù ba àwọn ẹni tí ń se rere. Ṣùgbọ́n àwọn tó ń ṣe búburú yóò máa bẹ̀rù rẹ̀ nígbà gbogbo. Nítorí ìdí èyí, pa òfin mọ́ ìwọ kò sì ní gbé nínú ìbẹ̀rù.

4. Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni láti ṣe ọ́ ní rere. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣé nǹkan búburú, máa bẹ̀rù, nítorí kò ru idà náà lásán. Nítorí ìránṣẹ́ Ọlọ́run nííse, ìránṣẹ́ ìbínú sí ara àwọn ẹni tí ń ṣe búburú.

5. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti tẹríba fún àwọn alásẹ, kì í ṣe nítorí ìjìyà tó lé wáyé nìkan, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí-ọkàn pẹ̀lú.

6. San owó orí rẹ pẹ̀lú nítorí ìdí méjì pàtàkì tí a ti sọ wọ̀nyí. Nítorí pé ó se dandan kí a san owó oṣù fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. Èyí yóò mú kí wọn tẹ̀ṣíwájú nínú iṣẹ́ Ọlọ́run náà. Wọn yóò sì máa tọ́jú yín.

7. Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo: owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí: owó-bodè fún ẹni tí owó-bodè tọ́ sí: ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù ń ṣe tirẹ̀; ọlá fún ẹni tí ọlá ń ṣe tirẹ̀

Ẹ Jẹ Gbésè Ìfẹ́

8. Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ní nígbésè, yàtọ̀ fún gbésè ìfẹ́ láti fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já.

9. Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panságà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ sọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.”

10. Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀: nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin.

11. Àti èyí, bí ẹ ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsìnyí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsìn yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ.

12. Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀.

13. Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmọ̀tipara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì íṣe ní ìjà àti ìlara.

14. Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jésù Kírísítì Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti ma mú ìfẹ́kúfẹ rẹ̀ ṣẹ.