orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ǹjẹ́ mo ní: Ọlọ́run ha ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù bí? Kí a má ri. Nítorí Ísírẹ́lì ni èmi pẹ̀lú, láti inú irú-ọmọ Ábúráhámù, ni ẹ̀yà Béńjámínì.

2. Ọlọ́run kò ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù ti ó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Tàbí ẹ̀yin kò mọ bí ìwé-mímọ́ ti wí ní ti Èlíjà? Bí ó ti ń bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì, wí pé:

3. “Olúwa, wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọn sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀; èmi nìkan soso ni ó sì kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi.”

4. Ṣùgbọ́n ìdáhùn wo ni Ọlọ́run fi fún un? “Mo ti paẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin ènìyàn mọ́ sílẹ̀ fún ara mi, àwọn tí kò tẹ eékún ba fún Báálì.”

5. ẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni li àkókò ìsinsin yìí pẹ̀lú, apákan wà nípa ìyànfẹ́ ti ore-ọ̀fẹ́.

6. í ó bá sì ṣe pé nípa ti ore-ọ̀fẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti iṣẹ́ mọ́; àyàmọ̀bí ore-ọ̀fẹ́ kì í ṣe ore-ọ̀fẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pe nípa ti iṣẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti ore-ọ̀fẹ́ mọ́; àyàmọ̀bí iṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ mọ́.

7. Kí ha ni? Ohun tí Isírẹ́lì ń wá kiri, òun náà ni kò rí; ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìyànfẹ́ ti rí i, a sì ṣé àyà àwọn ìyókù le.

8. Èyí ni ìwé Mímọ́ ń wí nígbà tí ó sọ pé:“Ọlọ́run ti fi oorun kùn wọ́n,ó sì dí ojú àti etí wọn,wọn kò sì le ní ìmọ̀ Kírísítì nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ síwọn.Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì rí títí di ọjọ́ òní.”

9. Ohun kan náà yìí ni Dáfídì ọba sọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé:“Kí oúnjẹ àti àwọn nǹkan mèremère wọn tàn wọ́n,láti rò pé wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run.Jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí padà dojú ìjà kọ wọ́n,kí a bá à lè fi òtítọ́ wó wọn túútúú.

10. Jẹ́ kí ojú wọn sókùnkùn, kí wọn má sì ṣe ríran.Sì jẹ́ kí ẹrù ńlá tẹ̀ wọ́n ba títí láéláé bí wọ́n ti ń rìn lọ.”

Ìran aláìkọlà Pín Nínú ìgbàlà Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì

11. Ǹjẹ́ èyí fi hàn wí pé: Ọlọ́run àwọn Júù rẹ ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ láéláé? Rárá o. Ṣe ni Ọlọ́run ń fi ìgbàlà fún àwọn aláìkọlà. Nípa síṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí àwọn Júù jowú, kí wọn sì béèrè ìgbàlà Ọlọ́run náà fún ara wọn.

12. Bí ó bá ṣe pé gbogbo ayé di ọlọ́rọ̀ nípa ìgbàlà tí Ọlọ́run fifún àwọn Júù nítorí pé wọ́n kọ ìgbàlà náà, ìbùkún tí ó tóbi jùlọ ni yóò tún jẹ́ fún wa nígbà tí àwọn Júù fúnra wọn yóò tún ní ìgbàlà náà pẹ̀lú wa.

13. Ṣebí ẹ̀yin náà mọ̀ pé Ọlọ́run ti yà mi sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ajíyìnrere fún àwọn aláìkọlà. Mo ń tẹnumọ́ ọn gidigidi mo sì ń rán àwọn Júù létí nípa rẹ̀ nígbákùúgbà tí ààyè bá wà.

14. Ìdí tí mo fi ń ṣe èyí ni láti mú kí wọn jowú nǹkan tí ẹ̀yin aláìkọlà ní, bóyá ní ọ̀nà yìí Ọlọ́run lè lò mí láti gba díẹ̀ là nínú wọn.

15. Ohun ìyanu ni yóò jẹ́ nígbà tí àwọn Júù yóò di Kírísítẹ́nì. Nígbà tí Ọlọ́run yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ṣe ni ó yípadà sí àwọn ìyókù ní ayé (àwọn aláìkọlà) láti fún wọn ní ìgbàlà. Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú nísinsinyí ìyanu náà ń peléke sí i ni nígbà tí àwọn Júù bá wá sọ́dọ̀ Kírísítì. Bí ẹni pé a sọ àwọn òkú di alààyè ni yóò jẹ́.

16. Níwọ̀n ìgbà tí Ábúráhámù àti àwọn wòlíì jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pẹ̀lú. Ìdí ni pé, bí gbòǹgbò igi bá jẹ́ mímọ́, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú.

17. Ṣùgbọ́n a ti ké díẹ̀ nínú ẹ̀ka Ábúráhámù, tí í ṣe àwọn Júù kúrò. Ẹ̀yin aláìkọlà, tí a lè wí pé ó jẹ́ ẹ̀ka igi búburú ni a fi sí ipò àwọn Júù. Nítorí náà, nísinsinyí, í se é ṣe fún yín láti gba ìbùkún tí Ọlọ́run ṣe ìpinnu fún Ábúráhámù àti àwọn ọmọ rẹ̀, èyí ni pé, ẹ ń pín nínú oúnjẹ ọlọ́ràá tí ó jẹ́ ti igi àrà ọ̀tọ̀ fún Ọlọ́run.

18. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe gbéraga nítorí pé a fi yín sí ipò àwọn ẹ̀ka tí a ké kúrò. Nǹkan tí ó mú kí ẹ ṣe pàtàkì ni pé, ẹ jẹ́ ẹ̀ka igi Ọlọ́run yìí. Ẹ rántí pé, ẹ̀ka igi lásán ni yín, ẹ kì í ṣe gbòngbò.

19. Ó ṣe é ṣe fún un yín kí ẹ wí pé, “Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti ké ẹ̀ka igi wọ̀nyí kúrò, tí ó sì fi wá sí ipò wọn, a sàn jù wọ́n lọ”

20. Ẹ kíyèsára! Ẹ sì rántí pé, a ké àwọn ẹ̀ka wọ̀n ọn nì tí í ṣe Júù kúrò nítorí pé wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́. Àti pé, ẹ̀yin sì wà níbẹ̀ nítorí pé ẹ̀yin gbàgbọ́. Ẹ má ṣe gbéraga, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀, kí ẹ sì dúpẹ́, kí ẹ sì, máa sọ́ra gidigidi.

21. Nítorí pé bí Ọlọ́run kò bá dá àwọn ẹ̀ka igi tí ó fi síbẹ̀ lákọ́kọ́ sí, ó dájú wí pé, kò ní dá ẹ̀yin náà sí.

22. Nítorí náà wo ore àti ìkáànú Ọlọ́run lórí àwọn tí ó subú, ìkàánú; ṣùgbọ́n lórí ìwọ, ọrẹ, bi ìwọ bá dúró nínú ọrẹ rẹ̀; kí a má bá ké ìwọ náà kúrò.

23. Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀.

24. Nítorí bí a bá ti ke ìwọ kúrò lára igi ólífì ìgbẹ́ nípa ẹ̀dá rẹ̀, tí a sì gbé ìwọ lé orí igi ólífì rere lòdì sí ti ẹ̀dá; mélòómélòó ni a ó lọ́ àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹ̀ka-ìyẹ́ka sára igi ólífì wọn?

Gbogbo Ísírẹ́lì Tòótọ́ Ni Yóò Ní Ìgbàlà

25. Ará, èmi kò sá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má baá ṣe ọlọgbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Ísírẹ̀lì ní apákan, títí kíkún àwọn aláìkọlà yóò fi dé.

26. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Ísírẹ́lì là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Ní Síónì ni Olúgbàlà yóò ti jáde wá,yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jákọ́bù.

27. Èyí sì ni májẹ̀mú mi fún wọn.Nígbà tí èmi yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”

28. Nípa ti ìyìn rere, ọ̀ta ni wọ́n nítorí yín; bí ó sì ṣe ti ìyànfẹ́ ni, olùfẹ́ ni wọ́n nítorí ti àwọn baba.

29. Nítorí àìlábámọ̀ li ẹ̀bùn àti ìpè Ọlọ́run.

30. Nítorí gẹ̀gẹ̀ bí ẹyin kò ti gba Ọlọ́run gbọ́ rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí tí ẹ̀yin rí ànú gbà nípa àìgbàgbọ́ wọn.

31. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn wọ̀nyí tí ó ṣe àìgbọ́ràn nísinsin yìí, kí àwọn pẹ̀lú bá le rí àánú gbà nípa àánú tí a fi hàn yín.

32. Nítorí Ọlọ́run sé gbogbo wọn mọ́ pọ̀ sínú àìgbàgbọ́, kí ó le ṣàánú fún gbogbo wọn.

33. A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run!Àwámáridí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí,ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ!

34. “Nítorí tali ó mọ inú Olúwa?Tàbí tani íṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?”

35. “Tàbí tani ó kọ́ fifún un,tí a kò sì san padà fún u?”

36. Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo;ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín.