Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 21:32-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Nítorí Jòhánù tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó-òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”

33. “Ẹ gbọ́ òwe mìíràn: Baálé ilé kan tí ó gbin àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ifúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé-ìsọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò.

34. Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá.

35. “Ṣùgbọ́n àwọn olágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹnì kínní, wọn pa èkèjì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹ́ta ní òkúta.

36. Lẹ́ẹ̀kejì, ó rán àwọn ìránṣẹ́ tí ó pọ̀ ju ti ìṣaájú sí wọn. Wọ́n sì tún ṣe bí ti àkọ́kọ́ sí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.

37. Níkẹyìn, baálé ilé yìí rán ọmọ rẹ̀ pàápàá sí wọn. Ó wí pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi.’

38. “Ṣùgbọ́n bí àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí ti rí ọmọ náà lókèèrè, wọ́n wí fún ara wọn pé, ‘Èyí ni àrólé náà. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì jogún rẹ̀.’

39. Wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú ọgbà, wọ́n sì pa á.

40. “Nítorí náà kí ni ẹ ní èrò wí pé olóko náa yóò ṣe pẹ̀lú àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí nígbà tí ó bá padà dé?”

41. Wọ́n wí pé, “Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, ní ipò òsì, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè.”

42. Jésù wí fún wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú ìwé Mímọ́ pé:“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,ni ó di pàtàkì igun ilé;Iṣẹ́ Olúwa ni èyí,ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’?

43. “Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn ẹlòmíràn tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá.

44. Ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta yìí yóò di fífọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí òun bá ṣubú lù yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”

45. Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí gbọ́ òwe Jésù, wọ́n mọ̀ wí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn.

46. Wọn wá ọ̀nà láti mú un, ṣùgbọ́n wọn bẹ̀rù ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bí wòlíì.

Ka pipe ipin Mátíù 21