Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 21:18-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ní òwúrọ̀ bí ó ṣe ń padà sí ìlú, ebi ń pa á.

19. Ó sì ṣàkíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lẹ́bàá ojú ọ̀nà, ó sì lọ wò ó bóyá àwọn èso wà lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ kan, ewé nìkan ni ó wà lórí rẹ̀. Nígbà náà ni ó sì wí fún igi náà pé, “Kí èso má tún so lórí rẹ mọ́.” Lójú kan náà igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì gbẹ.

20. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí èyí, ẹnú yà wọn, wọ́n béèrè pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ kíákíà?”

21. Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin bá lè ní ìgbàgbọ́ láì síyè méjì, nígbà náà ẹ̀yin yóò lè ṣe irú tí a se sí igi ọ̀pọ̀tọ́, Ẹ̀yin yóò lè sọ fún òkè yìí pé, ‘Yí ipò padà sínú òkun,’ yóò sì ríbẹ́ẹ̀.

22. Bí ẹ̀yin bá gbàgbọ́, ẹ̀yin lè rí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè nínú àdúrà gbà.”

23. Jésù wọ tẹ̀ḿpìlì, nígbà tí ó ń kọ́ni, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù tọ̀ ọ́ wá. Wọ́n béèrè pé “nípa àṣẹ wo ni o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó sì fún ọ ni àsẹ yìí?”

24. Jésù sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi yóò si bí yin léère ohun kan pàtọ́, bí ẹ̀yin bá lé sọ fún mi, nígbà náà èmi yóò sọ fún yín, àṣẹ tí Èmi fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí.

25. Níbo ni ìtẹ̀bọmi Jóhànù ti wa? Láti ọ̀run wá ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.”Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun yóò wí fún wa pé, ‘È é ha ti ṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’

26. Ní ìdà kejì, bí àwa bá sì sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì.”

27. Nítorí náà wọ́n sì dáhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí èyí, èmi kò ní sọ àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.

28. “Kí ni ẹ rò nípa eléyìí? Ọkùnrin kan ti ó ní àwọn ọmọkùnrin méjì. Ó sọ fún èyí ẹ̀gbọ́n pé, ‘Ọmọ, lọ ṣíṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’

29. “Ó sì dá baba rẹ̀ lóhùn pé, ‘Èmi kò ní í lọ,’ ṣùgbọ́n níkẹyìn ó yí ọkàn padà, ó sì lọ.

30. “Nígbà náà ni baba yìí tún sọ fún èyi àbúrò pé, ‘Lọ ṣiṣẹ́ ní oko.’ Ọmọ náà sì sọ pé, ‘Èmi yóò lọ, baba,’ ṣùgbọ́n kò lọ rárá.

31. “Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?”Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.”Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó-òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run ṣíwájú yín.

32. Nítorí Jòhánù tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó-òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”

33. “Ẹ gbọ́ òwe mìíràn: Baálé ilé kan tí ó gbin àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ifúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé-ìsọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò.

Ka pipe ipin Mátíù 21