Jésù wọ tẹ̀ḿpìlì, nígbà tí ó ń kọ́ni, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù tọ̀ ọ́ wá. Wọ́n béèrè pé “nípa àṣẹ wo ni o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó sì fún ọ ni àsẹ yìí?”