orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Oúnjẹ Tí A Fi Rúbọ Sí Òríṣà

1. Ní ìsinsinyìí, nípa tí oúnjẹ ti a fi rúbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé gbogbo wa ni a ní ìmọ̀, ìmọ̀ a máa fẹ́ mu ní gbéraga, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ní i gbéni ró.

2. Bí ẹnkẹ́ni bá ró pé òun mọ ohun kan, kò tí ì mọ̀ bí ó ti yẹ kí ó mọ̀.

3. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run nítòótọ́, òun ni ẹni tí a ṣí lójú sí ìmọ̀ àti òye Ọlọ́run.

4. Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà bí? Láì ṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé. A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kansoso ní ń bẹ, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo.

5. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ Ọlọ́run kékèké mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “Ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “Olúwa” wa).

6. Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan soso Jésù Kírísítì, nípaṣẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípaṣẹ̀ rẹ̀.

7. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí: Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsinyìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà; àti ẹ̀rì-ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́.

8. Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa buru julọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ.

9. Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsí ara gidigidi nípa ìlò òmìnira yín kí ẹ má baà mú kí àwọn arákùnrin mìíràn tí í se onígbàgbọ́, tí ọkàn wọn ṣe aláìlera, subú sínú ẹ́sẹ̀.

10. Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti iwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, lati jẹ oúnjẹ tí a fi rúbọ sí òrìsà?

11. Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kírísítì kú fún.

12. Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arakùnrin rẹ̀ tí ẹ sì n pá ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́sẹ̀ sí Kírísítì jùlọ.

13. Nítorí nàá, bí ẹran tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà bá máa mú arákùnrin mi dẹ́ṣẹ̀, èmi kì yóò jẹ́ ẹran mọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè, nítorí n kò fẹ́ kí arákùnrin mi ṣubú sìnù ẹ̀ṣẹ̀.