orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ẹ Yọ Alágbèrè Ọkùnrin Kúrò

1. Ìròyìn rẹ ń tàn kalẹ̀ pé ìwà, àgbérè wa láàrin yín, irú àgbérè tí a kò tilẹ̀ gbúròó rẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà pé, ẹnìkan nínú yín ń fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀.

2. Ẹ̀yin ń se ìgberaga, kí ni ṣe tí ojú kò tì yín, kí ẹ sì kún fún ìbànújẹ́, kí ẹ sì rí i pé ẹ yọ ọkùnrin náà tí ó hu ìwà yìí kúrò láàrin àwọn ọmọ ìjọ yín?

3. Lóòtọ́ èmi kò sí láàrin yín, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí àti pé, ní orúkọ Olúwa Jésù Kírísítì, mo tí ṣe ìdájọ̀ lórí irú ẹni bẹ́ẹ̀, bí ẹni pé mo wá láàrin yín.

4. Ní orúkọ Jésù Kírísítì. Nígbà tí ẹ̀yin bá péjọ, àti ẹ̀mí mi, pẹ̀lú agbára Jésù Kírísítì Olúwa wa.

5. Kí ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ lé sátanì lọ́wọ́ fún ìparun ara, kí ó baà le gba ẹ̀mí là ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì.

6. Ìfọ́nnú yín kò dára. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní i mú gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú?

7. Nítorí náà ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò nínú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ìyẹ̀fun titun, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà. Nítorí à ti fi ìrekọjá wa, àní Kírísítì ni a ti pa láti fi ṣe ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.

8. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa àjọ náà mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àrankan àti ìwà búburú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà òtítọ́ àti òdodo.

9. Nígbà tí mo kọ̀wé ṣáájú sí i yín, mo sọ fún yín pé, kí ẹ má ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbérè ènìyàn.

10. Nígbà tí mo sọ bẹ́ẹ̀ ń kò sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ayé yìí, tí wọn ń gbé ìgbé ayé wọn nínú ẹ̀ṣẹ̀: àgbérè, àti àwọn olójúkòkòrò tí ń rẹ́ ni jẹ, àwọn olè àti àwọn abọ̀rìṣà. Nítorí ó dájú pé ẹ̀yin gbọdọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti yẹra fún wọn.

11. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ń wí nínú ìwé sí i yín pé, ẹ kò gbọdọ̀ darapọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó bá pe ara rẹ̀ ni arákùnrin, ṣùgbọ́n tí ó fi ẹ̀ṣẹ̀ àgbérè tàbí wọ̀bìà, ìbọ̀rìṣà àti ẹlẹ́gàn tàbí ìmutípara àti alọ́nilọ́wọ́gbà. Ẹ má ṣe bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ oúnjẹ pọ̀ rárá.

12. Kì í ṣe iṣẹ́ mi láti máa ṣe ìdájọ́ (àwọn aláìgbàgbọ́) àwọn tí wọn kò sí nínú ìjọ. Dájúdájú iṣẹ́ tiwa ni láti ṣe ìdájọ́ àti láti fi ọwọ́ líle mú àwọn tí ń bẹ nínú ìjọ.

13. Ọlọ́run nìkan ni onídájọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. “Ẹ lé àwọn ènìyàn búburú náà kúrò láàrin yín.”