orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ mi, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ Kírísítì.

Ìbámu Nínú Ìsìn

2. Èmí yìn yín fún rírántí mi nínú ohun gbogbo àti fún didi gbogbo ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ yín mú sinsin gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi lélẹ̀ fún un yín.

3. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ̀yin mọ̀ pé, Kírísítì ni orí olukúlúkù ọkùnrin, orí obìnrin sì ni ọkọ rẹ̀ àti orí Kírísítì sì ní Ọlọ́run.

4. Gbogbo ọkùnrin tó bá borí rẹ̀ nígbà tó bá ń gbàdúrà tàbí sọtẹ́lẹ̀ kò bọ̀wọ̀ fún orí rẹ̀.

5. Bẹ́ẹ̀ náà ni obìnrin tí ó bá ń gbàdúrà tàbí tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ láìbo orí rẹ̀, kò bu ọlá fún orí ara rẹ̀ nítorí ọ̀kan náà ni pẹ̀lú ẹni tí ó fárí.

6. Ṣùgbọ́n tí obìnrin bá kọ̀ láti bo orí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó gé irun rẹ̀. Bí ó bá sì jẹ́ nǹkan ìtìjú fún un làti gé irun orí rẹ́, nígbà náà kí ó fi gèlè bo orí rẹ̀.

7. Ṣugbọ́n ọkùnrin kò ní láti fi nǹkan bo orí rẹ́ nígbà tí ó bá ń sìn, nítorí àwọrán àti ògo Ọlọ́run ni òun í ṣe, ṣùgbọ́n ògo ọkùnrin ni obìnrin í ṣe.

8. Ọkùnrin kò ti inú obìnrin wá, ṣùgbọ́n a yọ obìnrin jáde lára ọkùnrin,

9. bẹ́ẹ̀ ni a kò dá ọkùnrin fún àǹfààní obìnrin ṣùgbọ́n a da obìnrin fún ọkùnrin.

10. Nítorí ìdí èyí àti nítorí àwọn ańgẹ́lì, ni obìnrin ṣe gbọdọ̀ ní àmì àṣẹ rẹ̀ ní orí rẹ̀.

11. Ẹ rántí pé, nínú ètò Ọlọ́run obìnrin kò lè wà láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin kò lè wà láàsí obìnrin.

12. Lóòtọ́ láti ara ọkùnrin ni a ti yọ obìnrin jáde bẹ́ẹ̀ si ni ọkùnrin tipàsẹ obìnrin wa. Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ohun gbogbo ti wà.

13. Kí ni ẹ̀yìn fún ra yín rò lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún obìnrin láti máa gbàdúrà ní gbangba láìbo orí rẹ̀ bí?

14. Njẹ́ ìwà abínibí yín kò ha kọ́ yín pé, bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un.

15. Ṣùgbọ́n bí obìnrin bá ní irun gígún, ògo ni ó jẹ́ fùn un nítorí irun gígùn tí a fi fún un jẹ́ ìbòrí fún-ún.

16. Ṣùgbọ́n tí ẹnìkẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, ohun kan tí mo lè sọ sí gbogbo rẹ̀ ni pé, a kò ní àṣà tí ó yàtọ̀ sí èyí tí mo ti sọ, pé obìnrin gbọdọ̀ fi gèlè bo orí rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ tàbí tí ó bá ń gbàdúrà láàrin ìjọ Ọlọ́run.

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

17. Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá pé jọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú.

18. Lọ́nà kínní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrin yín ní ìgbà tí ẹ bá pé jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan.

19. Kò sí àníàní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrin yín, kí àwọn tí ó yanjú láàrin yín le farahàn kedere.

20. Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ.

21. Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olukúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkèjì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara.

22. Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kí ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.

23. Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Júdásì fi hàn, Olúwa Jésù Kírísítì mú búrẹ́dí.

24. Lẹ́yìn igbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.”

25. Bákan náà ló mu kọ́ọ̀bù ọtí wáìnì lẹ́yìn oúnjẹ, ó sì wí pé, “Kọ́ọ̀bù yìí ní májẹ̀mú titun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.”

26. Nítorí nígbákùúgbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú kọ́ọ̀bù yìí, ni ẹ tún sọ nipa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé.

27. Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú kọ́ọ̀bù Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.

28. Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáadáa kí ó tó jẹ lára àkàrà nàá àti kí ó tó mu nínú ife náà.

29. Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú kọ́ọ̀bù láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kírísítì áti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín.

30. Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń sàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn.

31. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáadáa, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́.

32. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ti Olúwa bá tilẹ̀ ṣe ìdájọ́ wa, tí ó sì jẹ wá níyà nítorí àwọn àṣìṣe wa, ó dára bẹ́ẹ̀, ó ń ṣe bẹ́ẹ̀, kí a má baà dá wa lẹ́jọ́, kí a sì pa wá run pẹ̀lú ayé.

33. Nítorí náà, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàkúùgbà ti ẹ bá péjọ láti jẹ́ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tàbi fún ìsìn oúnjẹ alẹ́ Olúwa, ẹ dúró de ara yín.

34. Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni nínú yin, kí ó jẹun láti ilé wá, kí ó má baá mú ìjìyà wá sórí ara rẹ̀ nígbà tí ẹ bá pé jọ.Tí mo bá dé, èmi yóò máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ ìyókù tí n kò ì ti fẹnu bà lẹ́sẹsẹ.