orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Pọ́ọ̀lù, ẹni ti a pé láti jẹ́ àpósítélì Kírísítì Jésù nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Sósíténì arákùnrin wa.

2. Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọ́ríńtì, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Jésù Kírísítì àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà.

3. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jésù Kírísítì.

Ìdúpẹ́

4. Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kírísítì Jésù.

5. Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo.

6. Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kírísítì ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín.

7. Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyì ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jésù Kírísítì.

8. Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì.

9. Ọlọ́run, nípaṣẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa, jẹ́ Olótítọ́.

Ìyapa Nínú Ìjọ Ọlọ́run

10. Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kírísítì, pé kí gbogbo yín fohùnsọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyàpá láàrin yín, àtipé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà.

11. Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kiloe sọ di mímọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrin yín.

12. Ohun tí mo ń sọ ni pé: Olúkúlùku yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Pọ́ọ̀lù”; “Èmi tẹ̀lé Àpólò”; òm̀íràn, “Èmi tẹ̀lé Kéfà, ìtúmọ̀, Pétérù”; àti ẹlòmìíràn, “Èmi tẹ̀lé Kírísítì.”

13. Ǹjẹ́ a há pín Jésù bí? Ṣé a kan Pọ́ọ̀lù mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀yín bọmi yín ní orúkọ Pọ́ọ̀lù bí?

14. Inú mi dún púpọ̀ pé èmi kò tẹ ẹnikẹ́ni nínú yín bọmi yàtọ̀ sí Kírísípù àti Gáíù.

15. Nítorí náà kò sí ẹni tí ó lè sọ pé òun ṣe ìtẹ̀bọmi ní orúkọ èmi fúnraara mi.

16. (Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún tẹ ìdílé Sítéfánà bọmi; lẹ́yìn èyí, èmí kò rántí pé mo tẹ ẹnikẹ́ni bọmi mọ́ níbikíbi).

17. Nítorí Kírísítì kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n Ó rán mi láti máa wàásù ìyìn rere: kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébú Kírísítì dí aláìlágbára.

Kírísítì Ní Ọgbọ́n Àti Agbára Ọlọ́run

18. Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń sègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run

19. Nítorí tí kọ ọ́ pé:“Èmi yóò pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run,òye àwọn olóye ni Èmi yóò sọ di asán.”

20. Àwọn ọlọ́gbọ́n ha dá? Àwọn ọ̀mọ̀wé ha dà? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ayé yìí ha dà? Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di òmùgọ̀?

21. Nítorí pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé kò le mọ̀ òun nípa ọgbọ́n àti ìṣeféfé wọn. Ó sì gba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa ìwàásù tí àwọn aráyé pè ní òmùgọ̀ àti ọ̀rọ̀ ọ yẹ̀yẹ́.

22. Nítorí pé àwọn Júù ń bèrè àmì, àwọn Gíríkì sí ń ṣàfẹ́rí ọgbọ́n:

23. ṣùgbọ́n àwọn ń wàásù Kírísítì ti a kàn mọ́ àgbélébùú, òkúta ìkọ̀sẹ̀ àwọn Júù àti òmùgọ̀ fún àwọn kèfèrí.

24. ṣùgbọ́n sí àwọn tí Ọlọ́run tí pè, àti àwọn Júù àti àwọn Gíríkì, Kírísítì ni agbára Ọlọ́run, àti ọgbọ́n Ọlọ́run.

25. Nítorí pé òmùgọ̀ Ọlọ́run jù ọgbọ́n ènìyàn lọ; àti aláìlera Ọlọ́run ni agbára jù ìlera ènìyàn lọ.

26. Ará, ẹ kíyèsí ohun tí nígbà tí a pè yín. Bí ó ti ṣe pé, kì í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn nípa ti ara, kí í ṣe ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà, kì ì ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́lá ni a pè.

27. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tí yàn àwọn òmùgọ̀ ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọ́run sì ti yàn àwọn ohun aláìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ni agbára.

28. Ó ti yan ètò tí ayé kẹ́gàn, tí wọn kò kà sí rárá, láti sọ nǹkan tí wọ́n kà sí ńlá di ohun asán àti aláìwúlò.

29. Nítorí kí ó má ba à sí ẹnìkan tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀.

30. Nítorí rẹ̀ ni ẹ̀yin ṣe wà nínú Kírísítì Jésù ẹni ti ó já sí ọgbọ́n fún wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run—èyi ń ni, òdodo, ìwà mímọ́ àti ìràpadà wa.

31. Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”