orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Ọ̀ta Kò Dawọ Àtakò Dúró

1. Nígbà tí Sáńbálátì, Tòbáyà Géṣémù ará Árábíà àti àwọn ọ̀taa wa tó kù gbọ́ pé, mo ti tún odi náà mọ, kò sì sí àlàfo kankan tí ó ṣẹ́ kù nínú un rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ì tí ì rì àwọn ìlẹ̀kùn ibodè ní àkókò náà.

2. Ṣáńbálátì àti Géṣémù rán iṣẹ́ yìí sí mi pé: “Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ónò.”Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbérò láti ṣe mí ní ibi;

3. Bẹ́ẹ̀ ni mo rán oníṣẹ́ padà pẹ̀lú èsì yìí pé; “Èmi ń ṣe iṣẹ́ ńlá kan, èmi kò le è sọ̀kalẹ̀ wá. Èéṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró, nígbà tí mo bá fi í sílẹ̀ tí mo sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá?”

4. Wọ́n rán iṣẹ́ náà sí mi nígbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mo sì fún wọn ní èsì bákan náà fún ìgbà kọ̀ọ̀kan.

5. Ní ìgbà kárùn-ún, Sáńbálátì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí mi pẹ̀lú irú iṣẹ́ kan náà, lẹ́tà kan tí a kò fi sínú apo ìwé wà ní ọwọ́ọ rẹ̀

6. tí a kọ sínú un rẹ̀ pé:“A ròyìn rẹ láàárin àwọn orílẹ̀ èdè—Géṣémù sì sọ pé, òtítọ́ ni, pé—ìwọ àti àwọn Júù ń gbérò láti ṣọ̀tẹ̀, nítorí náà ni ẹ ṣe ń mọ odi. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn yìí, ìwọ sì ń gbérò láti di ọba wọn

7. àti pé ó ti yan àwọn wòlíì kí wọn lè kéde nípa rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù: ‘ọba kan wà ní Júdà!’ Nísinsìn yìí, ìròyìn yìí yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọba; nítorí náà wá, jẹ́ kí a bá ara wa sọ̀rọ̀.”

8. Mo dá èsì yìí padà sí i pé: “Kò sí ohun kan nínú irú ohun tí ìwọ sọ tí ó ṣẹlẹ̀; ìwọ kàn rò wọ́n ní orí ara rẹ ni.”

9. Gbogbo wọn múra láti dẹ́rù bà wá, wọ́n ń rò ó wí pé, “Ọwọ́ wọn kò ní ran iṣẹ́ náà, àti wí pé wọn kò ní paríi rẹ̀.”Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà pé, “Nísinsìn yìí Ọlọ́run fi agbára fún ọwọ́ mi.”

10. Ní ọjọ́ kan mo lọ sí ilé Ṣemáyà ọmọ Deláyà, ọmọ Mehetabélì, ẹni tí a há mọ́ sínú ilé rẹ̀. Ó wí pé, “Jẹ́ kí a pàdé ní ilé Ọlọ́run nínú un tẹ́ḿpìlì, kí o sì jẹ́ kí a pa àwọn ìlẹ̀kùn tẹ́ḿpìlì dé, nítorí àwọn ènìyàn ń bọ̀ láti pa ọ́, ní òru ni wọn yóò wá láti pa ọ́.”

11. Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí irú ènìyàn bí èmi sá lọ? Tàbí kí ènìyàn bí èmi sá lọ sínú tẹ́ḿpìlì láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là? Èmi kò ní lọ!”

12. Èmi wòye pé Ọlọ́run kò rán-an, ṣùgbọ́n ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí mi nítorí Tòbáyà àti Sáńbálátì ti bẹ̀ẹ́ ní ọ̀wẹ̀.

13. Wọ́n bẹ̀ẹ́ ní ọ̀wẹ̀ láti dẹ́rù bà mí nítorí kí èmi lè dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣe èyí, kí wọn lè bà mí lórúkọ jẹ́, kí n sì di ẹni ẹ̀gàn.

14. A! Ọlọ́run mi, rántí Tòbáyà àti Ṣáńbálátì, nítorí ohun tí wọ́n ti ṣe; kí o sì tún rántí Nóádáyà wòlíì obìnrin àti àwọn wòlíì tókù tí wọ́n ń gbérò láti dẹ́rù bà mí.

Píparí Odi

15. Bẹ́ẹ̀ ni a parí odi náà ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Élúlì (oṣù kẹsán), láàrin ọjọ́ méjìléláàdọ́ta (52).

16. Nígbà tí àwọn ọ̀ta wa gbọ́ èyí, gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó yí wa ká bẹ̀rù jìnnìjìnnì sì mú wọn, nítorí wọ́n wòye pé iṣẹ́ yìí di ṣíṣe pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa.

17. Bákan náà, ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọlọ́láa Júdà ń kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà ránṣẹ́ sí Tòbáyà, èsì láti ọ̀dọ̀ Tòbáyà sì ń wá sí ọ̀dọ̀ wọn.

18. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júdà ti mulẹ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, nítorí tí ó jẹ́ àna Ṣekenáyà ọmọ Árà (Ṣáńbálátì fẹ́ ọmọ Ṣekenáyà) ọmọ rẹ̀ Jéhóhánánì sì tún fẹ́ ọmọbìnrin Méṣúlámì ọmọ Bérékíyà

19. ṣíwájú sí í, wọ́n túnbọ̀ ń ròyìn iṣẹ́ rere rẹ̀ fún mi, wọ́n sì ń sọ ohun tí mo sọ fún-un. Tòbáyà sì ń kọ àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí mi láti dẹ́rù bà mí.