orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Àlùfáà Àti Àwọn Ọmọ Léfì

1. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tí ó bá Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì àti Jéṣúà padà:Ṣeraiáyà, Jeremáyà, Éṣírà,

2. Ámáríyà, Málúkì, Hátúsì,

3. Ṣekánáyà, Réhúmù, Mérémótì,

4. Ídò, Gínétónì, Ábíjà,

5. Míjámínì, Móádáyà, Bílígà,

6. Ṣémááyà, Jóíáríbù, Jédááyà,

7. Ṣálù, Ámókì, Hílíkíyà, àti Jédáyà.Wọ̀nyí ni olóórí àwọn àlùfáà àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn ní ìgbà ayé e Jéṣúà.

8. Àwọn ọmọ Léfì ni Jéṣúà, Bínúì, Kádímálì, Ṣérébíà, Júdà àti Mátaníyà ẹ̀ni tí òun pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, ni àkóso orin ìdúpẹ́.

9. Bákíbúkíyà àti Húnì, àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn dúró sí ìdojúkojú wọn nínú ìsìn.

10. Jéṣúà ni baba Jòíákímù, Jòíákímù ni baba Élíáṣíbù, Élíáṣíbù ni baba Jóíádà,

11. Jóíádà ni baba Jònátanì, Jònátanì sì ni baba Jádúà.

12. Ní ìgbé ayé Jòíakímù, wọ̀nyí ni àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn àlùfáà:ti ìdílé Ṣeráiáyà, Méráyà;ti ìdílé Jeremáyà, Hananíyà;

13. ti ìdílé Éṣírà, Mésúlámù;ti ìdílé Ámáráyà, Jéhóhánánì;

14. ti ìdílé Málúkì, Jònátanì;ti ìdílé Ṣékánáyà, Jóṣéfù;

15. ti ìdílé Hárímù, Ádíná;ti ìdílé Mérémótì Hélíkáyì;

16. ti ìdílé Ídò, Ṣekaráyà;ti ìdílé Gínétónì, Mésúlámù;

17. ti ìdílé Ábíjà, Ṣíkírì;ti ìdílé Míníámínì àti ti ìdílé Móádíà, Pílítaì;

18. ti ìdílé Bílígà, Ṣámúyà;ti ìdílé Ṣémáyà, Jéhónátanì;

19. ti ìdílé Jóíáríbù, Máténáyì;ti ìdílé Jédáíáyà, Húsì;

20. ti ìdílé Ṣálù, Káláyì;ti ìdílé Ámókì, Ébérì;

21. ti ìdílé Hílíkíáyà, Háṣábíáyà;ti ìdílé Jédáíáyà, Nétanẹ́lì.

22. Àwọn olóórí ìdílé àwọn ọmọ Léfì ní ìgbà ayé Élíáṣíbù, Jóíádà, Jóhánánì àti Jádúà, àti pẹ̀lú ti àwọn àlùfáà ni a kọ sílẹ̀ ní ìgbà ìjọba Dáríúsì ará a Páṣíà.

23. Àwọn olórí ìdílé láàrin àwọn ọmọ Léfì títí di àkókò Jóhánánì ọmọ Élíáṣíbù ni a kọ sílẹ̀ nínú ìwé ìtàn.

24. Àti àwọn olóórí àwọn ọmọ Léfì ni Háṣábáyà, Ṣérébáyà, Jéṣúà ọmọ Kádímíélì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n dúró ní ìdojúkojúu wọn láti ròyìn àti láti dúpẹ́, apá kan ń dá èkejì lóhùn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run.

25. Mátanáyà, Bákíbúkáyà, Ọbadáyà, Mésúlámù, Tálímónì àti Ákúbù ni aṣọ́nà tí wọ́n ń ṣọ yàrá ìpamọ́ ní ẹnu ibodè.

26. Wọ́n ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ìgbà ayé e Jóíákímù ọmọ Jéṣúà, ọmọ Jósádákì, àti ní ọjọ́ ọ Nehemáyà baálẹ̀ àti ní ọjọ́ọ Ẹ́sírà àlùfáà àti akọ̀wé.

Ìyàsímimọ́ Odi Jérúsálẹ́mù.

27. Nígbà ìyàsímímọ́ odi Jérúsálẹ́mù a mú ọmọ Léfì jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí Jérúsálẹ́mù láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin síḿbálì, háápù àti dùùrù.

28. A kó àwọn akọrin náà jọ papọ̀ láti àwọn ìletò tí ó yí Jérúsálẹ́mù náà ká—láti àwọn abúlé Nétófátítì,

29. Láti Bétì Gílígálì, àti láti àwọn agbègbè Gébà àti Ásímáfétì, nítorí àwọn akọrin ti kọ́ àwọn ìletò fún ra wọn ní agbégbé Jérúsálẹ́mù.

30. Nígbà tí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n ya àwọn ènìyàn sí mímọ́, àti ẹnu ibodè àti odi pẹ̀lú.

31. Mo sì tún yan àwọn olórí Júdà láti gun orí odi náà. Mo sì tún yan àwọn ẹgbẹ́ akọrin ńlá méjì láti dúpẹ́. Àwọn kan yóò gòkè odi lọ sí apá ọ̀tún sí ọ̀nà ibodè Ààtàn.

32. Hósáyà àti ìdajì àwọn olórí Júdà tẹ̀lé wọn,

33. Àwọn wọ̀nyí náà sì lọ pẹ̀lúu wọn, Áṣáráyà, Éṣírà, Mésúlámù,

34. Júdà, Bẹ́ńjámínì, Ṣémáyà, Jeremáyà,

35. Pẹ̀lú àwọn àlùfáà díẹ̀ pẹ̀lú ipè (kàkàkí), pẹ̀lúu Ṣakaráyà ọmọ Jónátanì, ọmọ Ṣémáyà, ọmọ Matanáyà, ọmọ Míkáyà, ọmọ Ṣákúrì, ọmọ Áṣáfì,

36. Àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀—Ṣémáyà, Áṣárélì, Míláláì, gíláláì, Mááì, Nétanélì, Júdà àti Hánánì—pẹ̀lú ohun èlò orin bí àṣẹ Dáfídì ènìyàn Ọlọ́run. Éṣírà akọ̀wé ni ó sáájúu wọn bí wọ́n ti ń tò lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́.

37. Ní ẹnu ibodè oríṣun wọ́n ti ń lọ tààrà sí ọ̀nà ní orí àtẹ̀gùn ìlú Dáfídì ní orí òkè tí ó kángun sí odi, wọ́n sì gba ẹ̀gbẹ́ ilée Dáfídì kọjá títí dé ẹnu ibodè omi ní ìhà ìlà oòrùn.

38. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin kejì gba ọ̀nà òdì kejì lọ. Mo tẹ̀lé wọn ní orí odi, pẹ̀lú ìdajì àwọn ènìyàn, kọjá ilé ìṣọ́ ìléru lọ sí odi fífẹ̀,

39. Kọjá ẹnu ibodè Éúfúrẹ́mù ibodè Jéṣánà, ẹnu ibodè ẹja, ilé ìṣọ́ Hánánélì àti ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn—ún, títí dé ẹnu ibodè àgùntàn. Wọ́n sì dúró ní ibodè ìṣọ́.

40. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin méjèèjì tí wọ́n dúpẹ́ wà ní ààyè nínú ilé Ọlọ́run, èmi náà sì dúró ní ààyè mi pẹ̀lú ìdajì àwọn ìjòyè,

41. Àti àwọn àlùfáà—Élíákímù, Máṣéyà, Míníámínì, Míkáyà, Éliánáyì, Ṣaráyà àti Hananáyà pẹ̀lú àwọn ìpèe (kàkàkí) wọn.

42. Àti pẹ̀lú Maáṣéyà, Ṣémáyà, Éṣérì. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin ní abẹ́ ìṣàkóso Jéṣíráyà.

43. Ní ọjọ́ náà wọ́n rú ẹbọ ńlá, wọ́n ṣe àjọyọ̀ nítorí Ọlọ́run ti fún wọn ní ayọ̀ ńlá. Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé sì yọ̀ pẹ̀lú. A lè gbọ́ ariwo ayọ̀ tí ó jáde láti Jérúsálẹ́mù ní jìnnà réré.

44. Ní àkókò náà, a yan àwọn ènìyàn láti jẹ́ alábojútó yàrá ìkó ẹrù fún àwọn ọrẹ àkọ́so èso àti àwọn ìdámẹ́wàá. Láti inú àwọn oko tí ó wà ní àyíká ìlú ni wọ́n ti ní láti mú wá sínú yàrá ìkó nǹkan sí ìpín tí òfin sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, nítorí inú un àwọn ará a Júdà yọ́ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ, Léfì tó ń ṣiṣẹ ìránṣẹ.

45. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run wọn àti iṣẹ́ ìyàsímímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà, wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Dáfídì àti Sólómónì ọmọ rẹ̀ ti pa á láṣẹ fún wọn.

46. Ní ọjọ́ pípẹ́ ṣẹ́yìn ní ìgbà Dáfídì àti Áṣáfì, ni àwọn atọ́nisọ́nà, ti wà fún àwọn akọrin àti fún orin ìyìn àti orin ọpẹ́ sí Ọlọ́run.

47. Nítorí náà ní ìgbà ayé Ṣérúbábélì àti Nehemáyà, gbogbo Ísírẹ́lì ni ó ń dá ìpín lójoojúmọ́ fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà. Wọ́n sì tún yan ìpín mìíràn ṣọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Léfì tó kù àwọn ọmọ Léfì náà tún ya ìpín ti àwọn ọmọ Árónì sọ́tọ̀ fún wọn.