orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì rì àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Léfì.

2. Mo fún Hánánì arákùnrin mi pẹ̀lú Hananáyà olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jérúsálẹ́mù, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòótọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ.

3. Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ sí ìlẹ̀kùn Jérúsálẹ́mù títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.”

Àkọsílẹ̀ Orúkọ Àwọn Ìgbèkùn Tí Wọ́n Padà.

4. Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́.

5. Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà:

6. Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì ti kó ní ìgbékùn (wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà, olúkúlùkù sí ìlúu rẹ̀.

64. Àwọn wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í nibẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́;

66. Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n péjọ pọ̀ jẹ́ ẹgbàámọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó (42,360)

67. yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀tàdínlẹ́gbaàrin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún (245).

68. Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin (736): ìbáákà wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún (245);

69. Ràkunmí wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rinlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6720).

70. Díẹ̀ lára àwọn olóórí ìdílé náà kópa nínú un ṣíṣe iṣẹ́ náà Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún dírámásì wúrà, (kílò mẹ́jọ ààbọ̀) àádọ́ta bóòlù àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.

71. Díẹ̀ lára àwọn olóórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ọ̀kẹ́ méjì dírámásì wúrà (àádọ́sàn án kílò) (20,000) àti ẹgbọ̀kànlá mínà fàdákà (2,200) (tọ́ùn kan ààbọ̀).

72. Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì dírámásì wúrà, ẹgbẹ̀rùn-ún méjì mínà fàdákà àti ẹ̀tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.

73. Àwọn àlùfáà, àwọn Léfì, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì wà ní ìlúu wọn.Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú ìlúu wọn,