orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àtúnṣe Ìkẹyìn Tí Nehemáyà Ṣe.

1. Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Móṣè ṣókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú un rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn aráa Ámónì tàbí àwọn aráa Móábù sí àárin ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé.

2. Nítorí wọn kò mú oúnjẹ àti omi wá pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà, dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Bálámù ní ọ̀wẹ̀ láti gégùn-ún lé wọn lórí (Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa yí ègún náà padà sí ìbùkún).

3. Nígbà tí àwọn ènìyàn gbọ́ òfin yìí, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjòjì ènìyàn tí ó dara pọ̀ mọ́ wọn kúrò láàrin àwọn Ísírẹ́lì.

4. Ṣáájú èyí a ti fi Élíáṣíbù àlùfáà ṣe alákoṣo yàrá ìkó nǹkan ilé Ọlọ́run wa sí. Ó súnmọ́ Tóbíyà pẹ́kípẹ́ki.

5. Ó sì ti pèsè yàrá ńlá kan fún un, èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìtọ́jú ọrẹ ọkà, tùràrí àti àwọn ohun èlò tẹ́ḿpìlì àti ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró ti a fi lélẹ̀ bí ìlànà fún àwọn ọmọ Léfì, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà àti pẹ̀lúu gbogbo ọrẹ fún àwọn àlùfáà.

6. Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, èmi kò sí ní Jérúsálẹ́mù, nítorí pé ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n Aritaṣéṣéṣì ọba Bábílónì ni mo padà tọ ọba lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo gba ààyè lọ́dọ̀ọ rẹ̀.

7. Mo sì padà sí Jérúsálẹ́mù. Níhìn-ín ni mo ti mọ̀ nípa onírúurú ohun búburú tí Élíásíbù ti ṣe ní ti pípèṣè yàrá fún Tóbíyà nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run.

8. Kò tẹ́ mi lọ́rùn rárá, mo kó gbogbo ohun èlò ìdílée Tóbíyà dà síta láti inú iyàrá náà.

9. Mo pàṣẹ kí wọn ya àwọn iyàrá náà sí mímọ́, mo sì kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run padà síbẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti tùràrí.

10. Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Léfì, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ẹ wọn.

11. Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ọ wọn pé, “Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀?” Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀.

12. Gbogbo Júdà mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó—nǹkan sí.

13. Mo sì fi àlùfáà Ṣelemáyà, Ṣádókà akọ̀wé àti ọmọ Léfì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedáyà ṣe alákóṣo àwọn yàrá ìkó—nǹkan sí. Mo sì yan Hánánì ọmọ Ṣákúrì, ọmọ Mátanáyà bí olùrànlọ́wọ́ọ wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn.

14. Rántíì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo.

15. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Júdà tí wọ́n ń fún wáìnì ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé oríi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà.

16. Àwọn ará Tírè ti ń gbé nínú un Jérúsálẹ́mù ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti fún àwọn ọmọ Júdà.

17. Mo bá àwọn ọlọ́lá Júdà wí, mo wí fún wọn pé, “Èwo ni ohun búburú tí ẹ ń ṣe yìí ti ẹ ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.

18. Ṣé àwọn baba ńlá yín kòha ti ṣe nǹkan kan náà tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí wá oríi wa, àti sórí ìlú yìí? Báyìí, ẹ̀yin tún ń ru ìbínú ṣókè síi sórí Ísírẹ́lì nípa bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.”

19. Nígbà tí ojú ọjọ́ ń bora ní ẹnu ibodè Jérúsálẹ́mù, ṣáájú ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí a ti àwọn ìlẹ̀kùn, kí wọn má sì sí i títí tí ọjọ́ ìsinmi yóò fi kọjá. Mo yan àwọn ìránṣẹ́ẹ̀ mi láti ṣọ́ ẹnu ibodè, kí a má ba à lè gbé ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.

20. Ṣíbẹ̀, àwọn tí ń tà àti àwọn tí ń rà sùn ẹ̀yìn odi Jérúsálẹ́mù ní ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀méjì.

21. Ṣùgbọ́n mo kìlọ̀ fún wọn pé, “È é tí jẹ́ ti ẹ̀yin fi ń sùn ní ẹ̀yin odi ní òru? Bí ẹ̀yìn bá tún dán an wò mọ́, èmi yóò fi ọwọ́ líle mú un yín.” Láti ọjọ́ náà lọ, wọn kò sì wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́.

22. Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì pé kí wọn ya ara wọn sí mímọ́, kí wọn sì ṣọ́ ẹnu ibodè kí a lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.Tún rántíì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o sì fi àánú un rẹ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí i títóbi ìfẹ́ẹ̀ rẹ.

23. Ní ọjọ́ wọ̀n ọn nì, mo rí àwọn ọkùnrin Júdà tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin láti Áṣídódù, Ámónì àti Móábù.

24. Ìdajì àwọn ọmọ wọn ń sọ èdè Áṣídódù tàbí èdè ọ̀kan lára àwọn ènìyàn mìíràn tó kù, wọn kò sì mọ bí a ṣe ń ṣọ èdè Júdà.

25. Mo bá wọn wí mo sì gégùn-ún lé wọn lórí. Mo lu àwọn ènìyàn díẹ̀ nínú un wọn mo sì fa irun oríi wọn tu. Mo mú kí wọn búra ní orúkọ Ọlọ́run, kí wọn wí pé, “Ẹ̀yin kì yóò fi àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó tàbí fún ẹ̀yin tìkáara yín.

26. Kìí ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Sólómónì fi dá ẹ̀ṣẹ̀? Láàrin àwọn orìlẹ̀ èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀. Ọlọ́run rẹ̀ féràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lóríi gbogbo Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjòjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀.

27. Ǹjẹ́ ó ha yẹ kí àwa tún gbọ́ báyìí pé ẹ̀yin náà tún ń ṣe àwọn nǹkan tí ó burú jọjọ wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣe aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjòjì?”

28. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Jóíádà, ọmọ Élíásíbù olórí àlùfáà jẹ́ àna (o fẹ ọmọbìnrin) Ṣáńbálátì ará a Hórónì. Mo sì lé e jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.

29. Rántí, Ọlọ́run mi, nítorí wọ́n ti ba iṣẹ́ àlùfáà jẹ́ pẹ̀lú u májẹ̀mu iṣẹ́ àlùfáà àti ti àwọn Léfì.

30. Nítorí náà, mo ya àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì sí mímọ́ kúrò nínú un gbogbo ohun àjòjì, mo sì yan iṣẹ́ fún wọn, olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ẹ rẹ̀

31. Mo sì tún pèṣè fún ọrẹ, igi—pákó ní àkókò tí a yàn àti fún àwọn èso àkọ́so.Rántíì mi fún rere, Ọlọ́run mi.