orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Tí Ó Mọ Odi

1. Élíṣíbù olórí àlùfáà àti àwọn àlùfáà arákùnrin rẹ̀ lọ ṣiṣẹ́, wọ́n sì tún ibodè Àgùntàn mọ. Wọ́n yà á sí mímọ́, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn dúró sí ibi tí ó yẹ, wọ́n mọ ọ́n títí dé ilé ìṣọ́ Ọgọ́rùn ún, èyí tí wọ́n yà sí mímọ́ títí dé ilé ìṣọ́ gíga Hánálélì

2. Àwọn ọkùnrin Jẹ́ríkò sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Ṣákúrì ọmọ Ímírì sì mọ ní ẹ̀gbẹ̀ àwọn ọkùnrin Jẹ́ríkò.

3. Àwọn ọmọ Háṣénáyà ni wọ́n mọ Ìbodè Ẹja. Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn rẹ̀, ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè e rẹ̀ sí ààyè e wọn.

4. Mérémótì ọmọ Úráyà, ọmọ Hákóṣì tún èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn mọ. Ẹni tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni Mésúlámù ọmọ Bérékíà, ọmọ Méṣéábélì tún èyí ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ẹ wọn mọ. Bákan ńaà ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Ṣádókù ọmọ Báánà náà tún odi mọ.

5. Èyí tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn ni àwọn ọkùnrin Tẹ́kóà tún mọ, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́lá kò ṣe àtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà lábẹ́ àwọn olórí wọn.

6. Jóádà ọmọ Páṣéà àti Mésúlámù ọmọ Béṣódáyà ni wọ́n tún ẹnu ibodè àtijọ́ ṣe. Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn.

7. Lẹ́yìn in wọn ni àtúnṣe tún wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin Gíbíónì àti Mísípà: Mélátíà ti Gíbíónì àti Jádónì ti Mérónótì; àwọn ibi tí ó wà lábẹ́ àṣẹ baálẹ̀ agbègbè Éfúrétè.

8. Úsíélì ọmọ Hariháyà, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, tún ṣe àtúnṣe èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; àti Hananíyà, ọ̀kan lára awọn tí ó ń ṣe tùràrí, tún ṣe àtúnṣe èyí tí ó tún tẹ̀lé e. Wọ́n mú Jérúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò títí dé Odi Gbígbòòrò.

9. Réfájà ọmọ Húrì, alákòóṣo ìdajì agbègbè Jérúsálẹ́mù, tún èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣe.

10. Ní ẹ̀gbẹ́ èyí Jédáyà ọmọ Hárúmáfì tún èyí tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ilé rẹ̀ mọ, Hátúsì ọmọ Háṣábínéjà sì tún tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ.

11. Málíkíjà ọmọ Hárímù àti Háṣúbù ọmọ Páhátì—Móábù tún ẹ̀gbẹ́ kejì ṣe àti Ilé-ìṣọ́ Ìléru.

12. Ṣálúmù ọmọ Hálọ́ésì, alákóṣo ìdajì agbégbé Jérúsálẹ́mù tún ti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀

13. Ibodè Àfonífojì ni Hánúnì àti àwọn ará Ṣánóà tún mọ. Wọ́n tún-un kọ́ wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn àti àwọn ide rẹ̀ sí ààyè rẹ̀. Wọ́n sì tún tún ẹgbẹ̀rún-ún kan ìgbọ̀nwọ odi mọ títí dé ẹnu ibodè ààtàn.

14. Ẹnu ìbodè Ààtàn ni Málíkíjà ọmọ Rákábù, alákóṣo agbégbé Bẹti-Hákérémù tún mọ. Ó tún un mọ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìde rẹ̀ sí ààyè wọn.

15. Ẹnu Ìbodè Oríṣun ni Ṣálúnì ọmọ Kólí-Hóṣì, alákóṣo agbégbé Mísípà tún mọ. Ó tún ún mọ, ó kan òrùlé e rẹ̀ yíká, ó gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ àwọn ìdáiùú ìlẹ̀kùn àti àwọn idẹ rẹ̀ ró sí ààyè wọn. Ó tún tún odi Adágún Ṣílóámù mọ, ní ẹ̀gbẹ́ Ọgbà Ọba, títí dé àwọn àtẹ̀gùn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti ìlú Dáfídì.

16. Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Nehemáyà ọmọ Áṣíbúkù, alákóṣo ìdajì agbégbé Bétí Ṣúrì ṣe àtúnmọ dé ibì ọ̀ọ́kan ibojì Dáfídì, títí dé adágún omi àtọwọ́dá àti títí dé ilé àwọn alágbára.

17. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ará a Léfì, ní abẹ́ ẹ Réhúmù ọmọ Bánì. Lẹ́gbẹ̀ ẹ́ rẹ̀ ni Hásíábíà, alákóṣo ìdajì agbégbé Kéílà ṣe àtúnṣe fún agbégbé tirẹ̀.

18. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn arákùnrin wọn ṣe àtún-ṣe, Báfáyì ọmọ Hénádádì, alákóṣo àwọn ìdajì agbégbé kéílà.

19. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Éṣérì ọmọ Jéṣúà, alákóṣo Mísípà, tún ìbò mìíràn ṣe, láti ibìkan tí ó kojú sí ibi gíga sí ilé-ìhámọ́ra títí dé orígun.

20. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Bárúkù ọmọ Ṣábáyì fi ìtaa tún apá mìíràn ṣe, láti orígun dé ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù olórí àlùfáà.

21. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Mérémótì ọmọ Úráyà, ọmọ Hákósì tún apá mìíràn ṣe, láti ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù títí dé òpin rẹ̀

22. Àtúnṣe tí a tún tún ṣe lẹ́yìn rẹ̀ ní àwọn àlùfáà ní àyíká agbègbè tún ṣe.

23. Lẹ́yìn wọn ni Bẹ́ńjámínì àti Háṣíbù tún èyí ti iwájú ilé wọn ṣe; lẹ́yìn wọn ni, Ásáríyà ọmọ Máṣéyà ọmọ Ananíyà tún ti ẹ̀gbẹ́ ilé rẹ̀ ṣe.

24. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Bínúì ọmọ Hénádádì tún apá mìíràn ṣe, láti ilé Ásáríyà dé orígun àti kọ̀rọ̀,

25. àti Pálálì ọmọ Úṣáì tún ọ̀kánkán orígun ṣe àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde láti ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ààfin tòkè lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbégbé àwọn olùṣọ́. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Pédáyà ọmọ Párósì

26. àti àwọn ìránṣẹ́ẹ tẹ́ḿpìlì tí ó ń gbé ní òkè Ófélì ṣe àtúnṣe títí dé ibi ọ̀kánkán ibodè omi sí ìhà ìlà oòrùn àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde.

27. Lẹ́yìn wọn ni àwọn ènìyàn Tékóà tún apá mìíràn ṣe, láti ilé ìṣọ́ ńlá tí ó yọ sóde títí dé ògiri Ófélì.

28. Àwọn àlùfáà ni ó ṣe àtúnṣe òkè ibodè ẹsin ṣe, ẹnì kọ̀ọ̀kan ní iwájú ilée rẹ̀.

29. Lẹ́yìn wọn, Ṣádókì ọmọ Ímérì tún ọ̀kánkán ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣémáyà ọmọ Ṣekanáyà, olùṣọ́ ibodè ìhà ìlà oòrùn ṣe àtúnṣe.

30. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Hananáyà ọmọ Ṣelemáyà, àti Hánúnì ọmọ ẹ̀kẹfà Ṣáláfì, tún apá ibòmíràn ṣe. Lẹ́yìn wọn ni, Mésúlámù ọmọ Berekáyà tún ọ̀kánkán ibùgbé e rẹ̀ ṣe.

31. Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Mákíjà, ọ̀kan nínú àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn oníṣòwò, ní ọ̀kánkán ibodè àyẹ̀wò títí dé yàrá òkè kọ̀rọ̀;

32. àti láàárin yàrá òkè kọ̀rọ̀ àti ibodè àgùntàn ni àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà àti àwọn oníṣòwò tún ṣe.