orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Oúnjẹ Tó Mọ́ Àti Èyí Tí Kò Mọ́

1. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé,

2. “Ẹ sọ fún àwọn ara Ísírẹ́lì pé, ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń gbé lórí ilẹ̀ àwọn wọ̀nyí ni ẹ le jẹ.

3. Gbogbo ẹranko tí pátakò ẹsẹ̀ rẹ̀ bá là tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ.

4. “ ‘Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan. Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátakò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ràkunmí ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátakò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́.

5. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gára (ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta) ń jẹ apojẹ àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín.

6. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ehoro ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n kò ya pátakò ẹsẹ̀: àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín.

7. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹdẹ́ ya pátakò ẹṣẹ̀ ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín.

8. Ẹ má ṣe jẹ ẹran wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn. Àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.

9. “ ‘Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá tí ń gbé inú omi òkun, àti nínú odò: èyíkéyí tí ó bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ́.

10. Ṣùgbọ́n nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń gbé inú òkun àti nínú odò tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́, yálà nínú gbogbo àwọn tí ń rákò tàbí láàrin gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù tí ń gbé inú omi àwọn ni kí ẹ kórìíra.

11. Nígbà tí ẹ ti kórìíra wọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn: ẹ gbọdọ̀ kórìíra òkú wọn.

12. Ohunkóhun tí ń gbé inú omi tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́ gbọdọ̀ já sí ìríra fún yín.

13. “ ‘Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ni ẹ gbọdọ̀ kórìíra tí ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ wọ́n torí pé ohun ìríra ni wọ́n: idì, oríṣìiríṣìi igun,

14. Àwòdì àti onírúurú àṣá,

15. Onírúurú ẹyẹ ìwò,

16. Òwìwí, onírúurú ògòǹgò, onírúurú ẹ̀lúùlú, onírúurú àwòdì,

17. Òwìwí kéékèèkéé, onírúurú òwìwí,

18. Òwìwí funfun àti òwìwí ilẹ̀ pápá, àkàlàmàgbò,

19. akọ, onírúurú oódẹ, atọ́ka àti àdán.

20. “ ‘Gbogbo kòkòrò tí ń fò tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn ni wọ́n jẹ́ ìríra fún yín

21. irú àwọn kòkòrò oníyẹ́ tí wọn sì ń fi ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tí ẹ le Jẹ nìyí: Àwọn kòkòrò tí wọ́n ní ìsẹ́po ẹsẹ̀ láti máa fi fò lórí ilẹ̀.

22. Nínú àwọn wọ̀nyí ni ẹ lè jẹ onírúurú esú, onírúurú ìrẹ̀ àti onírúurú tata.

23. Ṣùgbọ́n gbogbo kòkòrò oníyẹ́ yóòkù tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin ni kí ẹ kórìíra.

24. “ ‘Nípa àwọn wọ̀nyí ni ẹ le fi sọ ara yín di àìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

25. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

26. “ ‘Àwọn ẹranko tí pátakò wọn kò là tan tàbí tí wọn kò jẹ àpọ̀jẹ jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú èyíkéyí nínú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́.

27. Nínú gbogbo ẹranko tí ń fi ẹṣẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tí ń fi èékánná wọn rìn jẹ́ aláìmọ́ fún yín: Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

28. Ẹni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Wọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín.

29. “ ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń rìn lórí ilẹ̀ ìwọ̀nyí ni ó jẹ́ àìmọ́ fún yín: Asé, eku àti orísirísi aláǹgbá,

30. Ọmọnílé, alágẹmọ, agílíńtí, ìgbín àti ọ̀gà.

31. Nínú gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ìwọ̀nyí jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

32. Bí ọ̀kan nínú wọn bá kú tí wọ́n sì bọ́ sórí nǹkan kan, bí ó ti wù kí irú ohun náà wúlò tó, yóò di aláìmọ́ yálà aṣọ ni a fi ṣe é ni tàbí igi, irun tàbí awọ, ẹ sọ ọ́ sínú omi yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́ lẹ́yìn náà ni yóò tó di mímọ́.

33. Bí èyíkéyí nínú wọn bá bọ́ sínú ìkòkò amọ̀, gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ti di àìmọ́. Ẹ gbọdọ̀ fọ ìkòkò náà.

34. Bí omi inú ìkòkò náà bá dà sórí èyíkeyí nínú oúnjẹ tí ẹ̀ ń jẹ oúnjẹ náà di aláìmọ́. Gbogbo ohun mímu tí a lè mú jáde láti inú rẹ̀ di àìmọ́.

35. Gbogbo ohun tí èyíkéyìí nínú òkú wọn bá já lé lórí di àìmọ́. Yálà ààrò ni tàbí ìkòkò ìdáná wọn gbọdọ̀ di fífọ́. Wọ́n jẹ́ àìmọ́. Ẹ sì gbọdọ̀ kà wọ́n sí àìmọ́.

36. Bí òkú wọn bá bọ́ sínú omi tàbí kànga tó ní omi nínú, omi náà kò di aláìmọ́ ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá yọ òkú wọn jáde tí ó fi ọwọ́ kàn-án yóò di aláìmọ́.

37. Bí òkú ẹranko wọ̀nyí bá bọ́ sórí ohun ọ̀gbìn tí ẹ fẹ́ gbìn wọ́n sì jẹ́ mímọ́.

38. Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ti da omi sí ohun ọ̀gbìn náà tí òkú wọn sì bọ́ sí orí rẹ̀ àìmọ́ ni èyí fún un yín.

39. “ ‘Bí ẹran kan bá kú nínú àwọn tí ẹ lè jẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú rẹ̀ yóò dí aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

40. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èyíkéyí nínú òkú ẹranko náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú ẹranko yóò fọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wà ní àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

41. “ ‘Ìríra ni gbogbo ohun tí ń rìn kákiri lórí ilẹ̀ jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n.

42. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ń rìn ká orí ilẹ̀ yálà ó ń fàyàfà tàbí ó ń fi ẹṣẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, tàbí ó ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣẹ̀ rìn ìríra ni èyí:

43. Ẹ má ṣe sọ ara yín di aláìmọ́ nípa èyíkéyí nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá wọ̀nyí. Ẹ má ṣe sọ ara yín dí àìmọ́ yálà láti ara wọn, tàbí nípaṣẹ̀ wọn.

44. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ torí pé mo jẹ́ mímọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípaṣẹ̀ ohunkóhun tí ń rìn kákiri lórí ilẹ̀.

45. Èmi ni Olúwa tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi.

46. “ ‘Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún ẹranko, ẹyẹ, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi àti àwọn ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀.

47. Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrin àìmọ́ àti mímọ́ láàrin ẹ̀dá alààyè, tí ẹ le jẹ àti èyí tí ẹ kò le jẹ.’ ”