orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìjìyà Fún Ẹ̀ṣẹ̀

1. Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ará Ísírẹ́lì tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrin Ísírẹ́lì, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún mólékì, kí wọ́n pa á, kí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa.

3. Èmi tìkarami yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ń ó sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ fún òrìṣà mólékì ó ti ba ibi mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú.

4. Bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá mójú kúrò lára irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún òrìṣà mólékì tí wọn kò sì pa irú ẹni bẹ́ẹ̀.

5. Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀, èmi yóò sì ge wọn kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọn: òun àti gbogbo àwọn tí ó dìjọ ṣe àgbérè tọ òrìṣà mólékì lẹ́yìn.

6. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbérè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀; Èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

7. “ ‘Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

8. Ẹ máa kíyèsí àṣẹ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́: Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.

9. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé bàbá tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé bàbá àti ìyá rẹ̀.

10. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládúgbò rẹ̀ lòpọ̀: ọkùnrin àti obìnrin náà ni kí ẹ sọ ní òkúta pa.

11. “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya bàbá rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù bàbá rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

12. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

13. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin mìíràn lòpọ̀ bí wọ́n í ti bá obìnrin lòpọ̀: àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìríra: pípa ni kí ẹ pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.

14. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ tìyatọmọ papọ̀: ìwà búburú ni èyí: iná ni kí ẹ fi sun wọ́n, òun àti àwọn méjèèjì, kí ìwà búburú má baà gbilẹ̀ láàrin yín.

15. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, ẹ gbọdọ̀ pa ọkùnrin náà àti ẹranko náà.

16. “ ‘Bí obìnrin kan bá sún mọ́ ẹranko tí ó sì bá a lòpọ̀ obìnrin náà àti ẹranko náà ni kí ẹ pa: ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì wà lórí ara wọn

17. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ arábìnrin rẹ̀ yálà ọmọbìnrin bàbá rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀, ohun ìtìjú ni èyí: Ẹ ó gé wọn kúrò lójú àwọn ènìyàn wọn: ó ti tàbùkù arábìnrin rẹ̀. Ẹ̀bi rẹ̀ yóò wá sórí rẹ̀.

18. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá sún mọ́ obìnrin, ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀. Ó ti tú orísun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òun náà sì gbà á láàyè. Àwọn méjèèjì ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọn.

19. “ ‘Má ṣe bá arábìnrin bàbá tàbí ti ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí o ti tú ìhòòhò ìbátan rẹ: Ẹ̀yin méjèèjì ni yóò ru ẹ̀bi yín.

20. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá aya arákùnrin bàbá rẹ̀ lòpọ̀ ó ti tàbùkù arákùnrin bàbá rẹ̀. A ó jẹ wọ́n ní ìyà; wọn yóò sì kú láìlọ́mọ.

21. “ ‘Bí ọkùnrin kan bá gba aya arákùnrin rẹ̀, ohun àìmọ́ ni èyí, ó ti tàbùkù arákùnrin rẹ̀, wọn ó wà láìlọ́mọ.

22. “ ‘Kí ẹ pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Kí ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín láti máa gbé má baà pọ̀ yín jáde.

23. Ẹ má ṣe tẹ̀lé àṣà àwọn orílẹ̀ èdè tí mo lé jáde níwájú yín torí pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ń ṣe, tí mo kóríra wọn.

24. Ṣùgbọ́n mo ti sọ fún yín pé, “Ẹ̀yin ni yóò jogún ilẹ̀ wọn; Èmi yóò sì fi fún yín láti jogún ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin.” Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn yòókù.

25. “ ‘Ẹ gbọdọ̀ pààlà sáàrin ẹran tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Láàrin ẹyẹ tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ àwọn ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkohun tí ń rìn lórí ilẹ̀: èyí tí mo yà sọ́tọ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun àìmọ́.

26. Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé èmi Olúwa fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀ èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi.

27. “ ‘Ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó jẹ́ abókúsọ̀rọ̀ tàbí oṣó láàrin yín ni kí ẹ pa. Ẹ sọ wọ́n ní òkúta, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.’ ”