Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremáyà 38:10-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nígbà náà ni Ọba pàṣẹ fún Ebedimélékì ará Kúṣì pé, “Mú ọgbọ̀n ọkùnrin láti ibí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì lọ yọ Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run kúrò nínú àmù kí ó tó kú.”

11. Ebedimélékì kó àwọn ọkùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n lọ sínú yàrá kan nínú ààfin Ọba. Ó mú àwọn aṣọ àkísà àti okùn tọ Jeremáyà lọ nínú àmù.

12. Ebedimélékì sọ fún Jeremáyà pé, “Fi àkísà àti okùn bọ abẹ́ abíyá rẹ, Jeremáyà sì ṣe bẹ́ẹ̀.”

13. Báyìí ni wọ́n ṣe yọ ọ́ jáde, ó sì ń gbé àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́.

14. Nígbà náà ni Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ pe, Jeremáyà òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti láti mú un wá sí ẹnubodè kẹta nílé Ọlọ́run. Ọba sì sọ fún Jeremáyà pé, “Èmi yóò bi ọ́ ní ohun kan; má sì ṣe fi ohun kan pamọ́ fún mi.”

15. Jeremáyà sì sọ fún Sedekáyà pé, “Tí mo bá fún ọ ní èsì, ṣé o kò ní pa mí? Tí mo bá gbà ọ́ nímọ̀ràn, o kò ní gbọ́ tèmi.”

16. Ṣùgbọ́n Ọba Sedekáyà búra ní ìkọ̀kọ̀ fún Jeremáyà wí pé, “Dájúdájú bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó fún wa ní ẹ̀mí, èmi kò ní pa ọ́ tàbí fà ọ́ fún àwọn tó ń lépa ẹ̀mí rẹ.”

17. Nígbà náà ni Jeremáyà sọ fún Sedekáyà pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Àyàfi bí o bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn olóyè Ọba Bábílónì, a ó dá ẹ̀mí rẹ sí àti pé ìlú yìí kò ní di jíjó níná; ìwọ àti ilé rẹ yóò sì wà láàyè.

18. Ṣùgbọ́n tí o kò bá jọ̀wọ́ ara rẹ fún àwọn ìjòyè Ọba Bábílónì, a ó fa ìlú yìí lé ọwọ́ àwọn Bábílónì. Wọn yóò sì fi ina sun-un, ìwọ gan-an kò ní le sá mọ́ wọn lọ́wọ́.’ ”

19. Ọba Sedekáyà sọ fún Jeremáyà pé, “Mò ń bẹ̀rù àwọn Júù tó ti sálọ sí ilẹ̀ Bábílónì, nítorí pé àwọn ará Bábílónì lè fà mí lé wọn lọ́wọ́ láti fìyà jẹ mí.”

20. Jeremáyà sì dáhùn wí pé, “Wọn kò ní fi ọ́ lé e lọ́wọ́. Pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́ nípa ṣíṣe ohun tí mo sọ fún ọ; yóò sì dára fún ọ, ẹ̀mí rẹ yóò sì wà.

21. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kọ̀ láti jọ̀wọ́ ara rẹ, èyí ni ohun tí Olúwa ti fi hàn mí:

22. Gbogbo àwọn obìnrin tó kù ní ààfin Ọba Júdà ni wọn yóò kó jáde fún àwọn ìjòyè Ọba Bábílónì. Àwọn obìnrin náà yóò sì sọ fún ọ pé:“ ‘Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàn ọ́ jẹ,wọ́n sì borí rẹ.Ẹsẹ̀ rẹ rì sínú orọ̀fọ̀;àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti fi ọ́ sílẹ̀.’

23. “Wọn yóò kó àwọn ìyàwó àti ọmọ rẹ wá sí Bábílónì. Ìwọ gan-an kò ní bọ́ níbẹ̀, Ọba Bábílónì yóò mú ọ, wọn yóò sì jó ìlú yìí kanlẹ̀.”

24. Nígbà náà ni Sedekáyà sọ fún Jeremáyà pé, “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, tàbí kí o kú.

25. Tí àwọn ìjòyè bá mọ̀ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n bá wá bá ọ wí pé, ‘Sọ fún wa ohun tí o bá Ọba sọ tàbí ohun tí Ọba sọ fún ọ; má ṣe fi pamọ́ fún wa tàbí kí a pa ọ́,’

26. nígbà náà kí o sọ fún wọn, ‘Mò ń bẹ Ọba láti má jẹ́ kí n padà lọ sí ilé Jónátanì láti lọ kú síbẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Jeremáyà 38