Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 4:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ ìnú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀.” Mósè sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyá rẹ̀, ní ìgbá ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

7. Ó sì wí pé, “Nísinsìnyìí, fi ọwọ́ náà padà sí abẹ́ aṣọ ní igbá àyà rẹ.” Mósè sì ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ́ sípò bí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tó kù.

8. Ní ìgba náà ni Olúwa wí pé; “Bí wọn kò bá gbà ọ́ gbọ́ tàbí kọ ibi ara sí iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, wọ́n le è ti ipaṣẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kejì gbàgbọ́.

9. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gba àwọn méjèèjì wọ̀nyí gbọ́, tí wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ, bu omi díẹ̀ láti inú odò Náílì kí o si dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi tí ìwọ bù láti inú odò yìí yóò sì di ẹ̀jẹ̀.”

10. Mósè sì sọ fún Olúwa pé, “Èmi jẹ́ akọ́lòlò, èmi kì í ṣe ẹni tó lè sọ̀rọ̀ já gaara láti ìgbà àtijọ wá tàbí láti ìgbà ti o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, mo jẹ́ ẹni ti ahọ́n rẹ̀ lọ́ tí ó sì ń lọ́ra àti sọ̀rọ̀.”

11. Olúwa sì sọ fún un pé, “Ta ni ó fún ènìyàn ni ẹnu? Ta ni ó mú un ya odi tàbí adití? Ta ni ó mú un ríran, tàbí mú un fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe Èmi Olúwa?

12. Lọ nísinsìnyìí, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò sì kọ́ ọ ni ohun ti ìwọ yóò sọ.”

13. Mósè dáhùn ó wí pé, “Olúwa jọ̀wọ́ rán ẹlòmíràn láti lọ ṣe iṣẹ́ yìí.”

14. Ìbínú Ọlọ́run ru sókè sí Mósè, ó sì sọ pé, “Árónì ará Léfì arákùnrin rẹ ńkọ́? Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ já gaara, ó ti wà ní ọ̀nà rẹ̀ báyìí láti pàdé e rẹ. Inú rẹ̀ yóò sì dùn ti ó bá rí ọ.

15. Ìwọ yóò sọ̀rọ̀ fún un, ìwọ yóò sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu: Èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò kọ́ ọ yín ni ohun ti ẹ ó ṣe.

16. Òun yóò bá ọ sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn, yóò sì dàbí i pé ẹnu un rẹ ni a gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ìwọ yóò sì dàbí Ọlọ́run ní iwájú rẹ̀.

17. Ṣùgbọ́n mú ọ̀pá yìí ni ọwọ́ rẹ kí ìwọ bá à lè fi ṣe àwọn iṣẹ́ àmì ìyanu pẹ̀lú rẹ̀.”

18. Mósè padà sí ọdọ Jẹ́tírò baba ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà tọ àwọn ènìyàn mi lọ ni ilẹ̀ Íjíbítí láti wò bóyá wọ́n sì wà láàyè ṣíbẹ̀.”Jẹ́tirò sì dáhùn, ó wí pé, “Má a lọ ni àlàáfíà.”

19. Nísínsìnyìí, Olúwa ti sọ fún Mósè ni ilẹ̀ Mídíánì pé, “Má a padà lọ sí Éjíbítì, nítorí àwọn ti ó fẹ́ pa ọ ti kú.”

20. Mósè mú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó kó wọn lé orí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí Éjíbítì. Ó sì mú ọ̀pa Ọlọ́run sí ọwọ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 4