Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 9:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdun kìn-ín-ní Dáríúsì ọmọ Áhásúérésì, ẹni tí a bí ní Médíà, òun ló jẹ ọba lórí ìjọba Bábílónì.

2. Ní ọdun kìn-ín-ní ijọba rẹ̀, èmi Dáníẹ́lì fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí wòlíì Jeremáyà, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jérúsálẹ́mù yóò fi wà ní ahoro.

3. Nígbà náà, ni mo yípadà sí Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú ààwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.

4. Mo gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́ wí pé:“Iwọ Olúwa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ó ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.

5. Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀.

6. Àwa kò fetí sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ sí àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé àti àwọn baba wa, àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà.

7. “Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Júdà, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti gbogbo Ísírẹ́lì ní gbogbo orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìsòótọ́ ọ wa sí ọ.

8. Áà! Olúwa, àwa àti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé, àti àwọn baba wa, ìtìjú dé bá wa nítorí àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.

9. Olúwa Ọlọ́run wa ní àánú, ó sì ń dáríjì, bí àwa tilẹ̀ ti ṣe ọ̀tẹ̀ síi;

10. Àwa kò gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run wa, a kò sì pa àwọn òfin rẹ mọ́, èyí tí ó fún wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.

11. Gbogbo Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀ sí òfin rẹ, wọ́n ti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbọràn sí ọ.“Nígbà náà ni ègún àti ìdájọ́ tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìbúra nínú òfin Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run dà sórí i wa, nítorí tí àwa ti sẹ̀ sí ọ.

12. Ìwọ ti mú ọ̀rọ̀ tí o sọ sí wa sẹ àti lórí àwọn alákòóso wa, nípa mímú kí ibi ńlá bá wa, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ọ̀run, bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù yìí.

13. Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Mósè bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ibi yìí ti dé bá wa, ṣíbẹ̀ a kò bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere Olúwa Ọlọ́run wa, nípa yíyí padà kí a kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì mọ òtítọ́ ọ rẹ.

14. Olúwa kò jáfara láti mú ibi náà wá sórí wa, nítorí Olódodo ni Olúwa Ọlọ́run wa nínú u gbogbo ohun tí ó ń ṣe; ṣíbẹ̀ àwa kò ṣe ìgbọ́ran sí i.

15. “Ní ìsinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, pẹ̀lú ọwọ́ agbára, tí ó fún ara rẹ̀ ní orúkọ tí ó wà títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búrurú.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 9