Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 11:6-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ wọn yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà, ọmọbìnrin ọba gúṣù yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ọba àríwá láti bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n òun kì yóò lè di agbára apá a rẹ̀ mú, bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò lè dá dúró, ṣùgbọ́n a ó tẹrí i rẹ̀ ba àti àwọn tí ó mú un wá, àti ọmọ tí ó bí, àti ẹni tí ó ń mu lọ́kàn le ní gbogbo àkókò wọ̀nyí.

7. “Ọ̀kan lára àwọn ìdílé e rẹ̀, ọmọbìnrin ọba Gúṣù yóò dìde láti gba ipò o rẹ̀. Yóò sì kọ lu ogun ọba àríwá, yóò sì wọ́ odi alágbára; yóò bá wọn jà yóò sì borí.

8. Yóò gba òrìṣà wọn, ère dídá àti ohun èlò oníye lórí ti fàdákà àti ti wúrà, yóò sì kó wọn lọ sí Éjíbítì. Fún ọdún díẹ̀ yóò fi ọba àríwá lọ́rùn sílẹ̀.

9. Nigbà náà, ni ọba àríwá yóò gbógun ti ilẹ̀ ọba, Gúṣù, ṣùgbọ́n yóò padà sí orílẹ̀ èdè Òun fúnra rẹ̀

10. Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò múra ogun wọn yóò kó ogun ńlá jọ, èyí tí a ó gbá lọ bí àgbàrá omi ńlá, yóò sì gbá a lọ títí dé ìlú olódi rẹ̀.

11. “Nígbà náà ni ọba Gúṣù yóò jáde pẹ̀lú ìbínú, yóò sì bá ọba àríwá jà, ẹni tí yóò kó ọmọ ogun púpọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ọba Gúṣù yóò borí i wọn.

12. Nígbà tí a bá kó ogun náà lọ, ọba Gúṣù yóò kún fún agbára, yóò sì pa ẹgbẹgbẹ̀rún ní ìpakúpa ṣíbẹ̀ kì yóò ṣẹ́gun.

13. Nítorí ọba àríwá yóò lọ kó ogun mìíràn jọ, tí ó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, yóò jáde pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun tí ó ti dira ogun fún dáradára.

14. “Ní àkókò ìgbà náà, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò dìde sí ọba Gúṣù. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò ṣọ̀tẹ̀ ní ìmúṣẹ ìran náà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí.

15. Nígbà náà ni ọba àríwá yóò wá yóò sì gbé ogun tìí, yóò sì kó ìlú olódi. Ogun ọba Gúṣù kò ní ní agbára láti kọjú ìjà sí i; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀wọ́ ogun tó dára jù kò ní ní agbára láti dúró.

16. Ẹni tí ó gbógun tìí yóò máa ṣe bí ó ti wù ú, kò sì sí ẹni tí yóò le è dojú kọ ọ́. Yóò sì fún ara rẹ̀ ní ibùjókòó ní ilẹ̀ tí ó dára, yóò sì ní agbára láti bàá jẹ́.

17. Yóò pinnu láti wá pẹ̀lú agbára ìjọba rẹ̀, yóò sì ní májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú ọba Gúṣù yóò sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún-un láti fẹ́ ẹ ní ìyàwó nítorí kí ó lè gba ìjọba, ṣùgbọ́n ète rẹ̀ yìí kì yóò ṣiṣẹ tàbí se ìrànlọ́wọ́ fún-un.

18. Nígbà náà ni yóò yí ara padà sí ilẹ̀ etí òkun, yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n aláṣẹ kan yóò mú òpin bá àfojúdi rẹ̀, yóò sì yí àfojúdi rẹ̀ padà sí orí i rẹ̀.

19. Lẹ́yìn èyí, yóò sì yí padà sí ìlú olódi ti orílẹ̀-èdè òun fún ra rẹ̀, ṣùgbọ́n yóò kọsẹ̀ yóò sì burú, a kì yóò sì ríi mọ́.

20. “Arọ́pò rẹ̀ yóò rán agbowó orí kan jáde láti fi ìdí ipò ọlá ọba múlẹ̀ ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n ọdún díẹ̀, a ó pa á run, kì yóò jẹ́ nípa ìbínú tàbí nínú ogun.

21. “Ẹni tí kò níláárí kan yóò rọ́pò rẹ̀, ẹni tí a kò tí ì fi ọlá ọba fún rí. Yóò sì gbógun sí ìjọba nígbà tí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀ láìbẹ̀rù, yóò sì gbà á pẹ̀lú àrékérekè.

22. Nígbà náà, ni a ó gbà ogunlọ́gọ̀ ogun kúrò níwájú u rẹ̀, pẹ̀lú òun àti ọmọ aládé ti májẹ̀mu náà ni a ó parun.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 11