Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 11:28-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè oun fúnra rẹ̀.

29. “Ní àsìkò tí a yàn, yóò gbógun sí Gúṣù lẹ́ẹ̀ kan sí i, ṣùgbọ́n ní ìgbà yí àyọrísí yóò yàtọ̀ sí ti ìṣáájú.

30. Nítorí pé, ọkọ̀ ojú omi àwọn ilẹ̀ etídò ìwọ̀-oòrùn yóò ta kòó, ọkàn rẹ̀ yóò sì pámi. Nígbà náà, ni yóò padà, yóò sì bínú sí májẹ̀mu mímọ́, yóò sì padà, yóò sì fi ojú rere hàn sí àwọn tí ó kọ májẹ̀mu mímọ́ náà.

31. “Agbára ọmọ ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹ́ḿpìlì jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀.

32. Pẹ̀lú ẹ̀tàn ni yóò bá àwọn tí ó ba májẹ̀mú jẹ́, ṣùgbọ́n, àwọn tí ó mọ Ọlọ́run wọn yóò jẹ́ alágbára. Wọn yóò sì kọjú ìjà sí i.

33. “Àwọn tí ó mòye yóò máa kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀, wọn yóò máa ṣubú nípa idà tàbí kí a jó wọn tàbí ìgbèkùn tàbí nípa ìkógún.

34. Nígbà tí wọ́n bá ṣubú, wọn yóò rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe aláìsòótọ́ yóò sì dara pọ̀ mọ́ wọn.

35. Lára àwọn tí ó mòye yóò kọsẹ̀, nítorí kí a baà tún wọn ṣe, wọ́n di mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ìgbà ìkẹyìn nítorí yóò sì wá ní àkókò tí a yàn.

36. “Ọba yóò ṣe bí ó ti wù ú yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, ju gbogbo òrìṣà lọ, yóò máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò-ṣe-é-gbọ́-létí sí Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run, a yóò sì máa yege títí àkókò ìbínú yóò fi parí, nítorí ohun tí a ti pinnu yóò ṣẹlẹ̀.

37. Òun kò ní ka òrìṣà àwọn baba rẹ̀ sí tàbí èyí tí àwọn fẹ́, òun kò ní ka ìkankan sí, ṣùgbọ́n yóò gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ.

38. Ṣùgbọ́n dípò wọn, yóò bu ọlá fún òrìṣà àwọn ìlú olódi: òrìṣà tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ni yóò bu ọlá fún pẹ̀lú wúrà àti fàdákà, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti ẹ̀bùn tí ó lówó lórí.

39. Yóò kọ lu àwọn ìlú olódi tí ó lágbára pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ òrìṣà àjèjì, yóò sì bu ọlá ńlá fún ẹni tí ó jẹ́wọ́ rẹ̀. Yóò mú wọn ṣe alákòóso lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí èrè.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 11