1. Ní ọdún kẹta tí Jéhóíákímù jẹ ọba Júdà, Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù, ó sì kọ lù ú pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀.
2. Olúwa sì fa Jéhóíákímù ọba Júdà lé e lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó lọ sí ilé òrìṣà ní Bábílónì, sí inú ilé ìṣúra òrìṣà a rẹ̀.
3. Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Áṣípénásì, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá.
4. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Bábílónì.
5. Ọba pèsè oúnjẹ ojoojúmọ́ àti wáìnì láti orí tábìlì i rẹ̀ fún wọn, ó sì kọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ fún ọba.
6. Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó wá láti Júdà: Dáníẹ́lì, Hananíáyà, Mísáẹ́lì àti Ásáríyà.
7. Olórí àwọn ìwẹ̀fà fún wọn ní orúkọ tuntun: Ó fún Dáníẹ́lì ní Beliteṣáṣárì, ó fún Hananíáyà ní Sádírákì, ó fún Mísáẹ́lì ní Mésákì àti Áṣáríyà ní Àbẹ́dinígò.