Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Ọba 13:5-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Olúwa pèsè Olùgbàlà fún Ísírẹ́lì, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Ṣíríà. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀.

6. Ṣùgbọ́n wọn kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jéróbóámù, èyí tí ó ti fa Ísírẹ́lì láti dá. Wọ́n tẹ̀ṣíwájú nínú rẹ̀ pẹ̀lú òpó Áṣérà dúró síbẹ̀ ní Ṣamáríà.

7. Kò sí ohùn kan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ti ọmọ ogun Jéhóáhásì àyàfi àádọ́ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, kẹ̀kẹ́ mẹ́wàá, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀, nítorí ọba Ṣíríà ti pa ìyókù run, ó sì ṣe wọ́n bí eruku nígbà pípa ọkà.

8. Fún ti ìyókù ìṣe Jéhóáhásì fún ìgbà, tí ó fi jọba, gbogbo ohun tí ó ṣe àti àṣeyọrí rẹ̀ ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

9. Jéhóáhásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sí Samáríà, Jéhóásì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

10. Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Jóásì ọba Júdà, Jéhóásì ọmọ Jéhóáhásì di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà ó sì jọba fún ọdún mẹ́rìndínlógún.

11. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì èyí tí ó ti ti Ísírẹ́lì láti fà. Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn.

12. Fún ti ìyókù iṣẹ́ Jéhóásì fún ìgbà tí ó fi jọba, gbogbo ohun tí ó ṣe, pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀ pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Ámásáyà ọba Júdà, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?

13. Jéhóásì sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. Jéróbóámù sì rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́. A sin Jéhóásì sí Samáríà pẹ̀lú àwọn ọba Ísírẹ́lì.

14. Nísinsìn yìí, Èlíṣà ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn, lọ́wọ́ èyí tí ó sì kú. Jéhóásì ọba Ísírẹ́lì lọ láti lọ wò ó, ó sì ṣunkún lórí rẹ̀. “Baba mi!, Baba mi!” Ó ṣunkún. “Àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin Ísírẹ́lì.!”

15. Èlíṣà wí pé, “Mú ọrun kan àti àwọn ọfà,” ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.

16. “Mú ọrun ní ọwọ́ rẹ.” Ó wí fún ọba Ísírẹ́lì. Nígbà tí ó ti mú u, Èlíṣà mú ọwọ́ rẹ̀ lé ọwọ́ ọba.

17. “Ṣí fèrèsé apá ìlà oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣéé: “Ta á!” Èlíṣà wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun Olúwa; ọfà ìṣẹ́gun lórí Ṣíríà!” Èlíṣà kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Ṣíríà run pátapáta ní Áfékì.”

18. Nígbà náà ó wí pé, “Mú àwọn ọfà náà,” ọba sì mú wọn. Èlíṣà wí fún un pé, “Lu ilẹ̀.” Ó lù ú lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró.

19. Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹẹ̀marùn-ún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹfà; Nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Ṣíríà àti pa á run pátapáta ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta péré.”

20. Èlíṣà kú a sì sin ín.Ẹgbẹ́ Àwọn ará Móábù máa ń wọ orílẹ̀ èdè ní gbogbo àmọ́dún.

Ka pipe ipin 2 Ọba 13