orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Dáfídì àti Jónátanì

1. Nígbà náà ni Dáfídì sá kúrò ní Naíótì ti Rámà ó sì lọ sọ́dọ̀ Jónátanì ó sì béèrè pé, “Kí ni mo ṣe? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Báwo ni mo ṣe ṣẹ baba rẹ, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí mi?”

2. Jónátanì dáhùn pé, “Kí a má rí i! Ìwọ kò ní kú! Wò ó baba mi kì í ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí tí ó kéré, láì fi lọ̀ mí. Èéṣe tí yóò fi fi èyí pamọ́ fún mi? Kò rí bẹ́ẹ̀.”

3. Ṣùgbọ́n Dáfídì tún búra, ó sì wí pé, “Baba rẹ mọ̀ dáradára pé mo rí ojú rere ní ojú ù rẹ, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, ‘Jónátanì kò gbọdọ̀ mọ èyí yóò sì bà á nínú jẹ́.’ Ṣíbẹ̀ nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láàyè àti gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà láàyè, ìgbésẹ̀ kan ni ó wà láàrin èmi àti ikú.”

4. Jónátanì wí fún Dáfídì pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe, èmi yóò ṣe é fún ọ.”

5. Dáfídì wí pé, “Wò ó, ọ̀la ni oṣù tuntun, mo sì gbọdọ́ bá ọba jẹun, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó lọ láti fi ara pamọ́ lórí pápá títí di àṣálẹ́ ọjọ́ kẹta.

6. Tí baba rẹ bá fẹ́ mi kù, sọ fún un pé, ‘Dáfídì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ààyè láti sáré lọ sí ìlú rẹ̀ nítorí wọ́n ń ṣe ẹbọ ọdọọdún ní ibẹ̀ fún gbogbo ìdílé rẹ̀.’

7. Tí o bá wí pé, ‘Ó dára náà,’ nígbà náà, ìránṣẹ́ rẹ wà láìléwu. Ṣùgbọ́n tí ó bá bínú gidigidi, ìwọ yóò mọ̀ dájú pé ó pinnu láti ṣe ìpalára mi.

8. Ṣùgbọ́n ní tirẹ ìwọ, fi ojú rere wo ìránṣẹ́ rẹ; nítorí tí ìwọ ti báa dá májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ níwájú Olúwa. Tí mo bá jẹ̀bi, pa mí fún ara rẹ! Èéṣe tí ìwọ yóò fi fi mí lé baba rẹ lọ́wọ́?”

9. Jónátanì wí pé, “Kí a má ríi! Ti mo bá ti gbọ́ tí baba mi ti pinnu láti pa ọ́ lára, ṣé èmi kò ní sọ fún ọ?”

10. Dáfídì sì béèrè pé, “Ta ni yóò sọ fún mi tí baba rẹ̀ bá dá ọ lóhùn ní ohùn líle?”

11. Jónátanì wí pé, “Wá, jẹ́ kí a jáde lọ sórí pápá.” Nígbà náà wọ́n sì jáde lọ.

12. Nígbà náà ni Jónátanì sọ fún Dáfídì: “Pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì, èmi yóò rí i dájú pé mo gbọ́ ti ẹnu baba mi ní ìwòyí ọ̀la tàbí ní ọ̀túnla tí ó bá sì ní ojú rere ní inú dídùn sí ọ, tí èmi kò bá ránṣẹ́ sí ọ, kí èmi sì jẹ́ kí o mọ̀?

13. Ṣùgbọ́n tí baba mi kò bá ní ìfẹ́ sí pa ọ́ lára, kí Olúwa kí ó dí ìyà jẹ mí, tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ; tí n kò bá jẹ́ kí o mọ̀, kí n sì jẹ́ kí o lọ ní àlàáfíà. Kí Olúwa kí ó pẹ̀lú ù rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹ̀lú baba mi.

14. Ṣùgbọ́n fi inú rere àìkùnà hàn mí. Níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè kí wọ́n má ba à pa mí,

15. Má ṣe ké àánú rẹ kúrò lórí ìdílé mi títí láé. Bí Olúwa tilẹ̀ ké gbogbo ọ̀ta Dáfídì kúrò lórí ilẹ̀.”

16. Nígbà náà ni Jónátanìf bá ilé Dáfídì dá májẹ̀mú wí pé, “Olúwa yóò pe àwọn àti Dáfídì láti sírò”

17. Jónátanì mú kí Dáfídì tún ìbúra ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní síi, nítorí tí ó fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn ara rẹ̀.

18. Nígbà náà ni Jónátanì wí fún Dáfídì pé, “Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a ó ò fẹ́ ọ kù, nítorí àyè rẹ yóò ṣófo.

19. Ní ọ̀túnla lọ́wọ́ alẹ́ lọ sí bi tí o sá pamọ́ sí nígbà tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀, kí o sì dúró níbi òkúta Ésélù.

20. Èmi yóò ta ọfà mẹ́ta sí ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀, gẹ́gẹ́ bí i pé mo ta á sí àmì ibìkan.

21. Èmi yóò rán ọmọdékùnrin kan èmi yóò wí fún un wí pé, ‘Lọ, kí o lọ wá ọfà náà.’ Tí mo bá sọ fún-un wí pé, ‘wò ó, ọfà wọ̀nyí wà ní ibi báyìí ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ rẹ;’ kó wọn wá síbí kí o sì wá, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wà ní ààyè, o wà ní àlàáfíà; kò sí ewú.

22. Ṣùgbọ́n tí mo bá sọ fún ọmọdékùnrin náà pé, ‘wò ó, àwọn ọfà náà kọjá níwájú rẹ;’ nígbà náà, o gbọdọ̀ lọ, nítorí Olúwa ti rán ọ jáde lọ.

23. Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi àti ìwọ jọ sọ, rántí Olúwa jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin ìwọ àti èmi títí láéláé.”

24. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì sá pamọ́ sínú pápá. Nígbà tí àṣè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun sì dé, ọba sì jókòó láti jẹun.

25. Ó sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ipò o rẹ̀ ní ibi tí ó máa ń ijòkòó lórí ìjòkó tí ó wà lẹ́gbẹ̀ ẹ́ ògiri, ní òdìkejì Jónátanì, Ábínérì sì jókòó ti Ṣọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n àyè Dáfídì sì ṣófo.

26. Ṣọ́ọ̀lù kò sọ nǹkan kan ní ọjọ́ náà, nítorí ó rò pé, “Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì láti jẹ́ kí ó di aláìmọ́ lótìítọ́ ó jẹ́ aláìmọ́.”

27. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dáfídì sì tún ṣófo. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún ọmọ rẹ̀ Jónátanì pé, “Kí ni ó dé tí ọmọ Jésè kò fi wá síbi oúnjẹ, lánàá àti lónìí?”

28. Jónátanì sì dáhùn pé, “Dáfídì bẹ̀ mí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fún ààyè láti lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

29. Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí n lọ, nítorí pé ìdílé wa ń ṣe ìrúbọ ní ìlú, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi sì ti pàṣẹ fún mi láti wà níbẹ̀; tí èmi bá rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí n lọ láti lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nì yí tí kò fi wá sí orí tábìlì oúnjẹ ọba.”

30. Ìbínú Ṣọ́ọ̀lù sì ru sí Jónátanì ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ búburú yìí, ṣé èmi kò ti mọ̀ pé, ìwọ ti yan ọmọ Jésè fún ìtìjú ti ara rẹ àti fún ìtìjú mọ̀mọ́ rẹ tí ó bí ọ?

31. Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jésè bá wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé, a kì yóò fi ẹṣẹ̀ ìwọ tàbí ti ìjọba rẹ múlẹ̀. Nísinsìn yìí ránṣẹ́ kí o sì lọ mú un wá fún mi, nítorí ó gbọ́dọ̀ kú!”

32. Jónátanì béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwa yóò fi pa á? Kí ni ó ṣe?”

33. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jónátánì láti gún un pa. Nígbà náà ni Jónátanì mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dáfídì ni.

34. Bẹ́ẹ̀ ni Jónátanì sì fi ìbínú dìde kúrò ni ibi oúnjẹ, kò sì jẹun ni ọjọ́ kejì oṣù náà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi fún Dáfídì, nítorí pé baba rẹ̀ dójú tì í.

Jónátanì kìlọ̀ fún Dáfídì.

35. Ó sì ṣe, ní òwúrọ̀ ni Jónátanì jáde lọ sí oko ní àkókò tí òun àti Dáfídì ti fí àdéhùn sí, ọmọdekùnrin kan sì wá pẹ̀lú rẹ̀.

36. Ó si wí fún ọmọdékùnrin rẹ̀ pé, “Sáré, kí o si wá àwọn ọfà tí èmi ó ta.” Bí ọmọdé náà sì ti ń sáré, òun sì tafà rékọjá rẹ̀.

37. Nígbà tí ọmọdékùnrin náà sì dé ibi ọfà tí Jónátanì ta, Jónátanì sì kọ sí ọmọdékùnrin náà ó sì wí pé, “Ọfà náà kò ha wà níwájú rẹ bi?”

38. Jónátanì sì kọ sí ọmọdékùnrin náà pé, “Sáré! Yára! Má ṣe dúró!” Ọmọdékùnrin Jónátanì sì ṣa àwọn ọfà náà, ó sì tọ olúwa rẹ̀ wá.

39. (Ọmọdékùnrin náà kò sì mọ̀ nǹkan; ṣùgbọ́n Jónátanì àti Dáfídì ni ó mọ ọ̀ràn náà.)

40. Jónátanì sì fí apó àti ọrun rẹ̀ fún ọmọdékùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Lọ, kí o sì mú wọn lọ sí ìlú Para.”

41. Bí ọmọdékùnrin náà ti lọ tán, Dáfídì sì dìde láti ibi òkúta náà, ó sì wólẹ̀, ó sì tẹríba ní ìdojúbolẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta fún Jónátanì: wọ́n sì fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọ́n sì jùmọ̀ sunkún, èkín-ín-ní pẹ̀lú ikejì rẹ̀, ṣùgbọ́n áfídì sunkún púpọ̀ jù.

42. Jónátanì sì wí fún Dáfídì pé, “Má a lọ ní àlàáfíà, bí o ti jẹ́ pé àwa méjèèjì tí júmọ búra ni orukọ Olúwa pé, ‘Ki Olúwa ó wà láàrin èmi àti ìwọ, láàrin irú-ọmọ mi àti láàrin irú-ọmọ rẹ̀ láéláé.’ ” Òun sì dìde, ó sì lọ kúrò: Jónátanì sì lọ sí ìlú.