orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Sámúẹ́lì 29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ákíṣì Rán Dáfídì Sí Síkílágì.

1. Àwọn Fílístínì sì kó gbogbo ogun wọn jọ sí Áfékì: Ísírẹ́lì sì dó ni ibi ìsun omi tí ó wà ní Jésírélì.

2. Àwọn ìjòyé Fílístínì sì kọjá ní ọ̀rọ̀ọ̀rún àti lẹ́gbẹgbẹ̀rún; Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Ákíṣì sì kẹ́yìn.

3. Àwọn ìjòyé Fílístínì sì béèrè wí pé, “Kín ni àwọn Hébérù ń ṣe nìhìn-ín yìí?”Ákíṣì sì wí fún àwọn ìjòyè Fílístínì pé “Dáfídì kọ yìí, ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì, tí ó wà lọ́dọ̀ mi láti ọjọ́ wọ̀nyí tàbí láti ọdún wọ̀nyí, èmi kò ì tì í rí àṣìṣe kan ni ọwọ́ rẹ̀ lati ọjọ́ tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.”

4. Àwọn ìjòyé Fílístínì sì bínú sí i; àwọn ìjòyé Fílístínì sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí ọkùnrin yìí padà kí ó sì lọ sí ipó rẹ̀ tí ó fi fún un, kí ó má sì jẹ́ kí ó bá wa sọ̀kalẹ̀ lọ sí ogun, kí ó má ba à jásí ọ̀ta fún wa ni ogun; Kín ni òun ó fi ba olúwa rẹ̀ làjà, orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọ́?

5. Ṣé èyí ni Dáfídì ti wọn torí rẹ̀ gberin ara wọn nínú ìjọ wí pé,“ ‘Ṣọ́ọ̀lù pa ẹgbẹgbẹrun rẹ̀,Dáfídì si pa ẹgbẹgbàárun tirẹ́.’ ”

6. Ákíṣì sì pe Dáfídì, ó sì wí fún un pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ìwọ jẹ́ ólóòótọ́ àti ẹni ìwà rere lójú mi, ní àlọ rẹ àti ààbọ̀ rẹ pẹ̀lú mi ní ogun: nítorí pé èmi ko tìí ri búburú kan lọ́wọ́ rẹ́ láti ọjọ́ ti ìwọ ti tọ̀ mí wá, títí o fi dì òní yìí ṣùgbọ́n lójú àwọn ìjòyè, ìwọ kò ṣe ẹni tí ó tọ́.

7. Ǹjẹ́ yípadà kí o sì máa lọ ní àlàáfíà, kí ìwọ má ṣe bà àwọn Fílístínì nínú jẹ́.”

8. Dáfídì sì wí fún Ákíṣì pé, “Kín ni èmi ṣe? Kín ni ìwọ sì rí lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ láti ọjọ́ ti èmi ti ń gbé níwájú rẹ títí di òní yìí, tí èmi kì yóò fi lọ bá àwọn ọ̀ta ọba jà.”

9. Ákíṣì sì dáhùn, ó sì wí fún Dáfídì pé, “Èmi mọ̀ pé ìwọ ṣe ẹni-rere lójú mi, bi ańgẹ́lì Ọlọ́run; ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Fílístínì wí pé, Òun kì yóò bá wa lọ sí ogun.

10. Ǹjẹ́, nísinsin yìí dìde ní òwúrọ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ tí ó bá ọ wá: ki ẹ si dìde ní òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ bá mọ́ kí ẹ sì máa lọ.”

11. Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì dìde ní òwúrọ̀ láti padà lọ sí ilẹ̀ àwọn Fílístínì. Àwọn Fílístínì sì gòkè lọ sí Jésírélì.