Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Ọba 18:6-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pín ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ dé láàrin ara wọn, Áhábù gba ọ̀nà kan lọ, Ọbadíà sì gba ọ̀nà mìíràn lọ.

7. Bí Ọbadíà sì ti ń rìn lọ, Èlíjà sì pàdé rẹ̀. Ọbadíà sì mọ̀ ọ́, ó dojú bolẹ̀, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni ní tòótọ́, Èlíjà, Olúwa mi?”

8. Èlíjà sì dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, lọ kí o sọ fún olúwa rẹ pé, ‘Èlíjà ń bẹ níhìn ín.’ ”

9. Ọbadíà sì béèrè pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ kí ni mo ha dá tí ìwọ fi ń fi ìránṣẹ́ rẹ lé Áhábù lọ́wọ́ láti pa?

10. Mo mọ̀ dájú pé bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ, kò sí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan tí olúwa mi kò ti rán ènìyàn lọ láti wò ọ́. Àti nígbà tí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan bá wí pé o kò sí, òun a sì mú kí wọ́n búra wí pé wọn kò rí ọ.

11. Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí, ìwọ wí fún mi pé kí n lọ sọ́dọ̀ olúwa mi, kí n sì wí pé, ‘Èlíjà ń bẹ níhìn ín.’

12. Èmi kò sì mọ ibi tí ẹ̀mí Olúwa yóò gbé ọ lọ nígbà tí mo bá fi ọ́ sílẹ̀. Bí mo bá lọ, tí mo sì sọ fún Áhábù, tí kò sì rí ọ, òun a sì pa mí. Ṣíbẹ̀ èmi ìránṣẹ́ rẹ bẹ̀rù Olúwa láti ìgbà èwe mi wá.

13. Ṣé Olúwa mi kò ha ti gbọ́ ohun tí mo ṣe nígbà tí Jésébélì ń pa àwọn wòlíì Olúwa? Mo fi ọgọ́rùn ún wòlíì Olúwa pamọ́ sínú ihò òkúta méjì, àràádọ́ta ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo sì fi omi àti oúnjẹ bọ́ wọn.

14. Ìwọ sì sọ fún mi nísinsìn yìí pé, kí n tọ olúwa mi lọ pé, ‘Èlíjà ń bẹ níhìn ín.’ Òun a sì pa mí!”

15. Èlíjà sì wí pé, “Bí Olúwa àwọn ọmọ ogun ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, ní tòótọ́ èmi yóò fi ara mi hàn fún Áhábù lónìí.”

16. Bẹ́ẹ̀ ni Ọbadíà sì lọ láti pàdé Áhábù, ó sì sọ fún un, Áhábù sì lọ láti pàdé Èlíjà.

17. Nígbà tí ó sì rí Èlíjà, ó sì wí fún un pé, “Ṣé ìwọ nìyìí, ìwọ tí ń yọ Ísírẹ́lì lẹ́nu?”

18. Èlíjà sì dá a lóhùn pé, “Èmi kò yọ Ísírẹ́lì lẹ́nu, bí kò ṣe ìwọ àti ilé bàbá rẹ. Ẹ ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, ẹ sì ń tọ Báálímù lẹ́yìn.

19. Nísinsìn yìí kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ láti pàdé mi lórí òkè Kámẹ́lì. Àti kí o sì mú àádọ́tàlénírinwó (450) àwọn wòlíì Báálì àti irinwó (400) àwọn wòlíì ère òrìṣà tí wọ́n ń jẹun ní tábìlì Jésébélì.”

20. Bẹ́ẹ̀ ni Áhábù ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì kó àwọn wòlíì jọ sí orí òkè Kámẹ́lì.

21. Èlíjà sì lọ ṣíwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yóò máa ṣiyèméjì? Bí Olúwa bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò sì wí ohun kan.

22. Nígbà náà ni Èlíjà wí fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù ní wòlíì Olúwa, ṣùgbọ́n, àádọ́tàlénírinwó (450) ni wòlíì Báálì.

23. Ẹ fún wa ní ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù méjì. Jẹ́ kí wọn kí ó sì yan ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan fún ara wọn, kí wọn kí ó sì ké e sí wẹ́wẹ́, kí wọn kí ó sì tò ó sí orí igi, kí wọn kí ó má ṣe fi iná sí i. Èmi yóò sì tún ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kejì ṣe, èmi yóò sì tò ó sórí igi, èmi kì yóò sì fi iná sí i.

24. Nígbà náà ẹ ó sì képe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, èmi yóò sì képe orúkọ Olúwa. Ọlọ́run náà tí ó fi iná dáhùn, òun ni Ọlọ́run.”Nígbà náà ni gbogbo àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára.”

Ka pipe ipin 1 Ọba 18