Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 12:27-42 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Bí ó bá jẹ́ pé agbára Beelisebulu ni èmi fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára wo ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà, àwọn ọmọ yín ni yóo ṣe onídàájọ́ yín.

28. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọrun ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọrun ti dé ba yín.

29. “Báwo ni ẹnìkan ṣe lè wọ ilé alágbára lọ, kí ó kó o lẹ́rù, bí kò bá kọ́kọ́ de alágbára náà? Bí ó bá kọ́kọ́ dè é ni yóo tó lè kó o lẹ́rù.

30. “Ẹni tí kò bá ṣe tèmi, ó lòdì sí mi. Ẹni tí kò bá máa bá mi kó nǹkan jọ, ó ń fọ́nká ni.

31. Ìdí nìyí tí mo fi sọ fun yín pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati gbogbo ìsọ̀rọ̀ òdì ni a óo dárí rẹ̀ ji eniyan; ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì.

32. Ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ọmọ-Eniyan yóo rí ìdáríjì. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì láyé yìí ati ní ayé tí ń bọ.

33. “Bákan-meji ni. Ninu kí ẹ tọ́jú igi, kí ó dára, kí èso rẹ̀ sì dára, tabi kí ẹ ba igi jẹ́, kí èso rẹ̀ náà sì bàjẹ́. Èso igi ni a fi ń mọ igi.

34. Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀ yìí! Báwo ni ọ̀rọ̀ yín ti ṣe lè dára nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò dára? Nítorí ohun tí ó bá kún inú ọkàn ni ẹnu ń sọ jáde.

35. Ẹni rere a máa sọ ọ̀rọ̀ rere jáde láti inú ìṣúra rere; eniyan burúkú a sì máa sọ ọ̀rọ̀ burúkú jáde láti inú ìṣúra burúkú.

36. “Ṣugbọn mo sọ fun yín pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí eniyan bá ń sọ láì ronú ni yóo dáhùn fún ní ọjọ́ ìdájọ́.

37. Nítorí nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo fi dá ọ láre; nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo sì fi dá ọ lẹ́bi.”

38. Ní àkókò náà ni àwọn kan ninu àwọn amòfin ati ninu àwọn Farisi bi í pé, “Olùkọ́ni, a fẹ́ rí àmì láti ọwọ́ rẹ.”

39. Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìran burúkú ati ìran oníbọkúbọ ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fi fún un àfi àmì Jona wolii.

40. Nítorí bí Jona ti wà ninu ẹja ńlá fún ọjọ́ mẹta tọ̀sán-tòru, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo wà ninu ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹta, tọ̀sán-tòru.

41. Àwọn ará Ninefe yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́, wọn yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí wọ́n ronupiwada nítorí iwaasu tí Jona wà fún wọn. Wò ó, ẹni tí ó ju Jona lọ ló wà níhìn-ín.

42. Ọbabinrin láti ilẹ̀ gúsù yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́ yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí ó wá láti ọ̀nà jíjìn láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni. Ẹ wò ó, ẹni tí ó ju Solomoni lọ ló wà níhìn-ín.

Ka pipe ipin Matiu 12