Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 10:8-24 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Máa lọ sí Giligali ṣiwaju mi. N óo wá bá ọ níbẹ̀ láti rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. Dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ meje, títí tí n óo fi dé, n óo sì sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.”

9. Yíyí tí Saulu yipada kúrò lọ́dọ̀ Samuẹli, Ọlọrun sọ ọ́ di ẹ̀dá titun. Gbogbo àwọn àmì tí Samuẹli sọ fún un patapata ni ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà.

10. Nígbà tí Saulu ati iranṣẹ rẹ̀ dé Gibea, ọ̀wọ́ àwọn wolii kan pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun bà lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ láàrin wọn.

11. Nígbà tí àwọn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i bí ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹlu àwọn wolii, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi? Àbí Saulu náà ti di wolii ni?”

12. Ọkunrin kan tí ń gbé ibẹ̀ bèèrè pé, “Ta ni baba àwọn wolii wọnyi?” Láti ìgbà náà ni ó ti di àṣà kí àwọn eniyan máa wí pé, “Àbí Saulu náà ti di wolii ni?”

13. Lẹ́yìn tí Saulu ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tán, ó lọ sí ibi pẹpẹ, ní orí òkè.

14. Arakunrin baba rẹ̀ rí òun ati iranṣẹ rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ ti lọ?”Saulu dáhùn pé, “Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni a wá lọ. Nígbà tí a wá wọn tí a kò rí wọn, a lọ sọ́dọ̀ Samuẹli.”

15. Arakunrin baba Saulu bá bi í pé, “Kí ni Samuẹli sọ fun yín?”

16. Saulu dáhùn pé, “Ó sọ fún wa pé, dájúdájú, wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣugbọn Saulu kò sọ fún un pé, Samuẹli sọ fún òun pé òun yóo jọba.

17. Samuẹli pe àwọn eniyan náà jọ siwaju OLUWA ní Misipa.

18. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Mo kó yín jáde wá láti Ijipti, mo gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn eniyan yòókù tí wọn ń ni yín lára.’

19. Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, Ọlọrun tí ó gbà yín kúrò lọ́wọ́ ìṣòro ati ìyọnu. Ẹ wí fún mi pé, ‘Yan ẹnìkan, tí yóo jọba lórí wa.’ Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.”

20. Nígbà náà ni, Samuẹli mú kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA, gègé sì mú ẹ̀yà Bẹnjamini.

21. Lẹ́yìn náà Samuẹli mú kí àwọn ìdílé ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini tò kọjá, gègé sì mú ìdílé Matiri. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé Matiri bẹ̀rẹ̀ sí tò kọjá, gègé sì mú Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣugbọn wọn kò rí i nígbà tí wọ́n wá a.

22. Wọ́n bi OLUWA pé, “Àbí ọkunrin náà kò wá ni?”OLUWA dá wọn lóhùn pé, “Ó ti farapamọ́ sí ààrin àwọn ẹrù.”

23. Wọ́n sáré lọ mú un jáde láti ibẹ̀. Nígbà tí ó dúró láàrin wọn, kò sí ẹni tí ó ga ju èjìká rẹ̀ lọ ninu wọn.

24. Samuẹli bá wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹni tí OLUWA yàn nìyí. Kò sí ẹnikẹ́ni láàrin wa tí ó dàbí rẹ̀.”Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 10