Nígbà tí àwọn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i bí ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹlu àwọn wolii, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi? Àbí Saulu náà ti di wolii ni?”