Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 15:19-32 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Ọba bá kọjú sí Itai ará Gati, ó sì bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá wa lọ? Pada, kí o lọ dúró ti ọba, àlejò ni ọ́, sísá ni o sá kúrò ní ìlú rẹ wá síhìn-ín.

20. Kò sì tíì pẹ́ pupọ tí o dé, kí ló dé tí o fi fẹ́ máa bá mi káàkiri ninu ìrìnkèrindò mi? Èmi gan-an nìyí, n kò tíì mọ ibi tí mò ń lọ. Pada kí àwọn ará ìlú rẹ gbogbo sì máa bá ọ lọ. OLUWA yóo fẹ́ràn ìwọ náà, yóo sì dúró tì ọ́.”

21. Ṣugbọn Itai dáhùn pé, “Kabiyesi, mo fi OLUWA búra, bí ẹ̀mí oluwa mi ọba tí ń bẹ láàyè, pé, ibikíbi tí o bá ń lọ ni n óo máa bá ọ lọ, kì báà tilẹ̀ já sí ikú.”

22. Dafidi dáhùn, ó ní, “Kò burú.” Itai ati àwọn eniyan rẹ̀, ati àwọn ọmọ kéékèèké, tò kọjá níwájú ọba.

23. Gbogbo ìlú bú sẹ́kún bí àwọn eniyan náà ti ń lọ. Ọba rékọjá odò Kidironi, àwọn eniyan rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Gbogbo wọ́n jọ ń lọ sí ọ̀nà apá ijù.

24. Sadoku, alufaa, wà láàrin wọn, àwọn ọmọ Lefi sì wà pẹlu rẹ̀, wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí lọ́wọ́. Wọ́n gbé e kalẹ̀ títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi jáde kúrò ní ìlú. Abiatari, alufaa náà wà láàrin wọn.

25. Ọba wí fún Sadoku pé, “Gbé Àpótí Ẹ̀rí náà pada sí ìlú. Bí inú OLUWA bá dùn sí mi, bí mo bá bá ojurere OLUWA pàdé, yóo mú mi pada, n óo tún fi ojú kan Àpótí Ẹ̀rí náà ati ilé OLUWA.

26. Ṣugbọn bí inú rẹ̀ kò bá dùn sí mi, kí ó ṣe mí bí ó bá ti tọ́ ní ojú rẹ̀.”

27. Ó tún fi kún un fún Sadoku pé, “Wò ó! Ìwọ ati Abiatari, ẹ pada sí ìlú ní alaafia, mú Ahimaasi, ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari lọ́wọ́.

28. N óo dúró ní ibi tí wọ́n ń gbà la odò kọjá ní ijù níhìn-ín, títí tí n óo fi rí oníṣẹ́ rẹ.”

29. Sadoku ati Abiatari bá gbé àpótí ẹ̀rí pada sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀.

30. Ṣugbọn Dafidi gun gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi lọ, láì wọ bàtà, ó ń sọkún bí ó ti ń lọ, ó sì fi aṣọ bo orí rẹ̀ láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, tí wọ́n ń bá a lọ náà fi aṣọ bo orí wọn, wọ́n sì ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ.

31. Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé, Ahitofeli ti darapọ̀ mọ́ ọ̀tẹ̀ tí Absalomu ń dì, Dafidi gbadura sí OLUWA, ó ní, “Jọ̀wọ́, OLUWA, yí gbogbo ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá fún Absalomu pada sí asán.”

32. Nígbà tí Dafidi gun òkè náà dé orí, níbi tí wọ́n ti máa ń rúbọ sí Ọlọ́run, Huṣai, ará Ariki, wá pàdé rẹ̀ pẹlu aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya, ó sì ti ku eruku sí orí rẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 15